Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #225 Translated in Yoruba

وَلَا تَنْكِحُوا الْمُشْرِكَاتِ حَتَّىٰ يُؤْمِنَّ ۚ وَلَأَمَةٌ مُؤْمِنَةٌ خَيْرٌ مِنْ مُشْرِكَةٍ وَلَوْ أَعْجَبَتْكُمْ ۗ وَلَا تُنْكِحُوا الْمُشْرِكِينَ حَتَّىٰ يُؤْمِنُوا ۚ وَلَعَبْدٌ مُؤْمِنٌ خَيْرٌ مِنْ مُشْرِكٍ وَلَوْ أَعْجَبَكُمْ ۗ أُولَٰئِكَ يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَاللَّهُ يَدْعُو إِلَى الْجَنَّةِ وَالْمَغْفِرَةِ بِإِذْنِهِ ۖ وَيُبَيِّنُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
E ma fi awon aborisa lobinrin saya titi won yo fi gbagbo ni ododo. Dajudaju erubinrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lobinrin, koda ki aborisa lobinrin jo yin loju. E ma si fi onigbagbo ododo lobinrin fun awon aborisa lokunrin titi won yo fi gbagbo ni ododo. Erukunrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lokunrin, koda ki aborisa lokunrin jo yin loju. Awon (aborisa) wonyen n pepe sinu Ina. Allahu si n pepe sinu Ogba Idera ati aforijin pelu iyonda Re. O si n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le lo iranti
وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ ۖ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِي الْمَحِيضِ ۖ وَلَا تَقْرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطْهُرْنَ ۖ فَإِذَا تَطَهَّرْنَ فَأْتُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ أَمَرَكُمُ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ التَّوَّابِينَ وَيُحِبُّ الْمُتَطَهِّرِينَ
Won si n bi o leere nipa nnkan osu (obinrin). So pe: “Inira ni (sisunmo won lasiko naa). Nitori naa, e yera fun awon obinrin l’asiko nnkan osu. E ma se sunmo won (fun oorun ife) titi won yo fi se imora. Ti won ba si ti se imora, e sunmo won ni aye ti Allahu pa lase fun yin. Dajudaju Allahu nifee awon oluronu-piwada. O si nifee awon olumora
نِسَاؤُكُمْ حَرْثٌ لَكُمْ فَأْتُوا حَرْثَكُمْ أَنَّىٰ شِئْتُمْ ۖ وَقَدِّمُوا لِأَنْفُسِكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ مُلَاقُوهُ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
Awon obinrin yin, oko ni won fun yin. E lo s’inu oko yin bi e ba se fe, ki e si ti (ise rere) siwaju fun emi ara yin. E beru Allahu. Ki e mo pe dajudaju e maa pade Re. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu
وَلَا تَجْعَلُوا اللَّهَ عُرْضَةً لِأَيْمَانِكُمْ أَنْ تَبَرُّوا وَتَتَّقُوا وَتُصْلِحُوا بَيْنَ النَّاسِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
E ma se fi Allahu se ikewo fun ibura yin pe e o nii se rere, e o nii sora (nibi iwa ese), e o si nii se atunse laaarin awon eniyan. Allahu ni Olugbo, Onimo
لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِنْ يُؤَاخِذُكُمْ بِمَا كَسَبَتْ قُلُوبُكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Allahu ko nii fi ibura yin ti ko ti inu yin wa bi yin, sugbon O maa fi ohun ti o ba t’inu okan yin wa bi yin. Allahu ni Alaforijin, Alafarada

Choose other languages: