Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #178 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ مِنَ الْكِتَابِ وَيَشْتَرُونَ بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۙ أُولَٰئِكَ مَا يَأْكُلُونَ فِي بُطُونِهِمْ إِلَّا النَّارَ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ اللَّهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti Allahu sokale ninu Tira, ti won si n ta a ni owo pooku, awon wonyen ko je kini kan sinu won bi ko se Ina. Allahu ko si nii ba won soro ni Ojo Ajinde, ko si nii fo won mo (ninu ese). Iya eleta-elero si wa fun won
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ اشْتَرَوُا الضَّلَالَةَ بِالْهُدَىٰ وَالْعَذَابَ بِالْمَغْفِرَةِ ۚ فَمَا أَصْبَرَهُمْ عَلَى النَّارِ
Awon wonyen ni awon t’o fi imona ra isina, (won tun fi) aforijin ra iya. Bawo ni won se maa le sefarada fun Ina na
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ نَزَّلَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ ۗ وَإِنَّ الَّذِينَ اخْتَلَفُوا فِي الْكِتَابِ لَفِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ
Iyen ri bee nitori pe dajudaju Allahu so Tira (al-Ƙur’an) kale pelu ododo. Dajudaju awon t’o si yapa Tira naa ti wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)
لَيْسَ الْبِرَّ أَنْ تُوَلُّوا وُجُوهَكُمْ قِبَلَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَلَٰكِنَّ الْبِرَّ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَالْمَلَائِكَةِ وَالْكِتَابِ وَالنَّبِيِّينَ وَآتَى الْمَالَ عَلَىٰ حُبِّهِ ذَوِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ وَالسَّائِلِينَ وَفِي الرِّقَابِ وَأَقَامَ الصَّلَاةَ وَآتَى الزَّكَاةَ وَالْمُوفُونَ بِعَهْدِهِمْ إِذَا عَاهَدُوا ۖ وَالصَّابِرِينَ فِي الْبَأْسَاءِ وَالضَّرَّاءِ وَحِينَ الْبَأْسِ ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ صَدَقُوا ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُتَّقُونَ
Ki i se ohun rere ni ki e koju si agbegbe ibuyo oorun ati ibuwo oorun, amo (oluse) rere ni enikeni t’o ba gbagbo ninu Allahu, Ojo Ikeyin, awon molaika, Tira (al-Ƙur’an), ati awon Anabi. Tohun ti ife ti oluse-rere ni si owo, o tun n fi owo naa tore fun awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu, onirin-ajo (ti agara da), awon atoroje ati (itusile) l’oko eru. (Eni rere) yo maa kirun, yo si maa yo Zakah. (Eni rere ni) awon t’o n mu adehun won se nigba ti won ba se adehun ati awon onisuuru nigba airina-airilo, nigba ailera ati l’oju ogun esin. Awon wonyen ni awon t’o se (ise) ododo. Awon wonyen, awon si ni oluberu (Allahu)
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِصَاصُ فِي الْقَتْلَى ۖ الْحُرُّ بِالْحُرِّ وَالْعَبْدُ بِالْعَبْدِ وَالْأُنْثَىٰ بِالْأُنْثَىٰ ۚ فَمَنْ عُفِيَ لَهُ مِنْ أَخِيهِ شَيْءٌ فَاتِّبَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ وَأَدَاءٌ إِلَيْهِ بِإِحْسَانٍ ۗ ذَٰلِكَ تَخْفِيفٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَرَحْمَةٌ ۗ فَمَنِ اعْتَدَىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَلَهُ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se esan gbigba nibi ipaniyan ni oran- anyan fun yin. Olominira fun olominira, eru fun eru, obinrin fun obinrin. Enikeni ti won ba samoju kuro kini kan fun lati odo omo iya (eni ti won pa, ki eni ti o maa gba owo emi dipo emi) se ohun rere tele (owo ti o gba, ki eni ti o maa san’wo emi) san owo naa fun un ni ona t’o dara. Iyen ni igbefuye ati aanu lati odo Oluwa yin. Sugbon enikeni ti o ba tayo enu-ala (ofin) leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un

Choose other languages: