Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #57 Translated in Yoruba

هَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا تَأْوِيلَهُ ۚ يَوْمَ يَأْتِي تَأْوِيلُهُ يَقُولُ الَّذِينَ نَسُوهُ مِنْ قَبْلُ قَدْ جَاءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ فَهَلْ لَنَا مِنْ شُفَعَاءَ فَيَشْفَعُوا لَنَا أَوْ نُرَدُّ فَنَعْمَلَ غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ ۚ قَدْ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Ki ni won n reti bi ko se imuse oro Re? Lojo ti imuse oro Re ba de, awon t’o gbagbe re siwaju yoo wi pe: “Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu ododo wa. Nitori naa, nje a le ri awon olusipe, ki won wa sipe fun wa tabi ki won da wa pada sile aye, ki a le se ise miiran yato si eyi ti a maa n se?” Dajudaju won ti se emi won lofo. Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di ofo mo won lowo
إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ ۗ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ ۗ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n fi oru bo osan loju, ti oru n wa osan ni kiakia. Oorun, osupa ati awon irawo ni won ti ro pelu ase Re. Gbo! TiRe ni eda ati ase. Ibukun ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
ادْعُوا رَبَّكُمْ تَضَرُّعًا وَخُفْيَةً ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُعْتَدِينَ
E pe Oluwa yin pelu iraworase ati ohun jeeje. Dajudaju (Allahu) ko feran awon alakoyo
وَلَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَاحِهَا وَادْعُوهُ خَوْفًا وَطَمَعًا ۚ إِنَّ رَحْمَتَ اللَّهِ قَرِيبٌ مِنَ الْمُحْسِنِينَ
E ma sebaje lori ile leyin atunse re. E pe Allahu pelu iberu ati ireti. Dajudaju aanu Allahu sunmo awon oluse-rere
وَهُوَ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا أَقَلَّتْ سَحَابًا ثِقَالًا سُقْنَاهُ لِبَلَدٍ مَيِّتٍ فَأَنْزَلْنَا بِهِ الْمَاءَ فَأَخْرَجْنَا بِهِ مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ ۚ كَذَٰلِكَ نُخْرِجُ الْمَوْتَىٰ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
Oun ni Eni t’O n ran ategun (t’o je) iro idunnu siwaju aanu Re, titi (ategun naa) yoo fi gbe esujo t’o wuwo, ti A si maa wo o lo si oku ile. Nigba naa, A maa fi so omi kale. A si maa mu orisirisi eso jade. Bayen ni A o se mu awon oku jade nitori ki e le lo iranti

Choose other languages: