Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #47 Translated in Yoruba

وَنَزَعْنَا مَا فِي صُدُورِهِمْ مِنْ غِلٍّ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهِمُ الْأَنْهَارُ ۖ وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي هَدَانَا لِهَٰذَا وَمَا كُنَّا لِنَهْتَدِيَ لَوْلَا أَنْ هَدَانَا اللَّهُ ۖ لَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ ۖ وَنُودُوا أَنْ تِلْكُمُ الْجَنَّةُ أُورِثْتُمُوهَا بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
A o si mu inunibini kuro ninu okan won. Awon odo yo si maa san ni isale won. Won yoo so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O fi wa mona yii. Awa iba ti mona, ti ki i ba se pe Allahu to wa si ona. Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu ododo wa.” Won si maa pe won pe: “Iyen ni Ogba Idera ti A jogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise.”
وَنَادَىٰ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ أَصْحَابَ النَّارِ أَنْ قَدْ وَجَدْنَا مَا وَعَدَنَا رَبُّنَا حَقًّا فَهَلْ وَجَدْتُمْ مَا وَعَدَ رَبُّكُمْ حَقًّا ۖ قَالُوا نَعَمْ ۚ فَأَذَّنَ مُؤَذِّنٌ بَيْنَهُمْ أَنْ لَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الظَّالِمِينَ
Awon ero inu Ogba Idera yoo pe awon ero inu Ina pe: "A ti ri ohun ti Oluwa wa se adehun re fun wa ni ododo. Nje eyin naa ri ohun ti Oluwa yin se adehun (re fun yin) ni ododo?" Won yoo wi pe: “Bee ni.” Olupepe kan yo si pepe laaarin won pe: "Ki ibi dandan Allahu maa be lori awon alabosi
الَّذِينَ يَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا وَهُمْ بِالْآخِرَةِ كَافِرُونَ
(Awon ni) awon t’o n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo. Awon si tun ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin
وَبَيْنَهُمَا حِجَابٌ ۚ وَعَلَى الْأَعْرَافِ رِجَالٌ يَعْرِفُونَ كُلًّا بِسِيمَاهُمْ ۚ وَنَادَوْا أَصْحَابَ الْجَنَّةِ أَنْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ ۚ لَمْ يَدْخُلُوهَا وَهُمْ يَطْمَعُونَ
Gaga yoo wa laaarin ero inu Ogba Idera ati ero inu Ina. Awon eniyan kan maa wa lori ogiri (gaga naa), won yo si da eni kookan (ijo mejeeji) mo pelu ami won. Won yoo pe awon ero inu Ogba Idera pe: “Ki alaafia maa be fun yin.” Won ko i wo (inu) re, won si ti n jerankan (re)
وَإِذَا صُرِفَتْ أَبْصَارُهُمْ تِلْقَاءَ أَصْحَابِ النَّارِ قَالُوا رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Nigba ti won ba yiju won si ogangan awon ero inu Ina, won yoo so pe: “Oluwa wa, ma fi wa sodo awon ijo alabosi.”

Choose other languages: