Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Ayahs #17 Translated in Yoruba

وَلَيَحْمِلُنَّ أَثْقَالَهُمْ وَأَثْقَالًا مَعَ أَثْقَالِهِمْ ۖ وَلَيُسْأَلُنَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَمَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Dajudaju won yoo ru eru ese tiwon ati awon eru ese kan mo eru ese tiwon. Ati pe dajudaju A oo bi won leere ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n da ni adapa iro
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ إِلَّا خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ الطُّوفَانُ وَهُمْ ظَالِمُونَ
Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O gbe laaarin won fun egberun odun afi aadota odun. Ekun-omi si gba won mu nigba ti won je alabosi
فَأَنْجَيْنَاهُ وَأَصْحَابَ السَّفِينَةِ وَجَعَلْنَاهَا آيَةً لِلْعَالَمِينَ
A si la oun ati awon ero inu oko oju-omi. A si se won ni ami fun gbogbo eda
وَإِبْرَاهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاتَّقُوهُ ۖ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ
(Ranti Anabi) ’Ibrohim. Nigba ti o so fun ijo re pe: “E josin fun Allahu. Ki e si paya Re. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo.”
إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا ۚ إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا فَابْتَغُوا عِنْدَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ ۖ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
E kan n josin fun awon orisa leyin Allahu. E si n da adapa iro. Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Allahu, won ko ni ikapa arisiki kan fun yin. E wa arisiki si odo Allahu. Ki e josin fun Un. Ki e si dupe fun Un. Odo Re ni won yoo da yin pada si

Choose other languages: