Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #64 Translated in Yoruba

وَأَعِدُّوا لَهُمْ مَا اسْتَطَعْتُمْ مِنْ قُوَّةٍ وَمِنْ رِبَاطِ الْخَيْلِ تُرْهِبُونَ بِهِ عَدُوَّ اللَّهِ وَعَدُوَّكُمْ وَآخَرِينَ مِنْ دُونِهِمْ لَا تَعْلَمُونَهُمُ اللَّهُ يَعْلَمُهُمْ ۚ وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ شَيْءٍ فِي سَبِيلِ اللَّهِ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنْتُمْ لَا تُظْلَمُونَ
E pese sile de won nnkan ija ti agbara yin ka ninu nnkan amusagbara ati awon esin ori iso, ti eyin yoo fi maa deru ba ota Allahu ati ota yin pelu awon miiran yato si won, ti eyin ko mo won – Allahu si mo won. – Ohunkohun ti e ba na loju ona (esin) Allahu, A oo san an pada fun yin ni kikun; A o si nii se abosi fun yin
وَإِنْ جَنَحُوا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Ti won ba te sibi (eto) alaafia (fun dida ogun duro), iwo naa te sibe, ki o si gbarale Allahu. Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo
وَإِنْ يُرِيدُوا أَنْ يَخْدَعُوكَ فَإِنَّ حَسْبَكَ اللَّهُ ۚ هُوَ الَّذِي أَيَّدَكَ بِنَصْرِهِ وَبِالْمُؤْمِنِينَ
Ti won ba tun fe tan o je, dajudaju Allahu a to o. Oun ni Eni ti O fi aranse Re ati awon onigbagbo ododo ran o lowo
وَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ ۚ لَوْ أَنْفَقْتَ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مَا أَلَّفْتَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ أَلَّفَ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Allahu pa okan won po mora won. Ti o ba je pe o na gbogbo nnkan ti n be lori ile patapata, iwo ko le pa okan won po mora won. Sugbon Allahu pa okan won po mora won, dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَسْبُكَ اللَّهُ وَمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Iwo Anabi, Allahu ti to iwo ati awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo

Choose other languages: