Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #65 Translated in Yoruba

وَإِنْ جَنَحُوا لِلسَّلْمِ فَاجْنَحْ لَهَا وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Ti won ba te sibi (eto) alaafia (fun dida ogun duro), iwo naa te sibe, ki o si gbarale Allahu. Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo
وَإِنْ يُرِيدُوا أَنْ يَخْدَعُوكَ فَإِنَّ حَسْبَكَ اللَّهُ ۚ هُوَ الَّذِي أَيَّدَكَ بِنَصْرِهِ وَبِالْمُؤْمِنِينَ
Ti won ba tun fe tan o je, dajudaju Allahu a to o. Oun ni Eni ti O fi aranse Re ati awon onigbagbo ododo ran o lowo
وَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ ۚ لَوْ أَنْفَقْتَ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مَا أَلَّفْتَ بَيْنَ قُلُوبِهِمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ أَلَّفَ بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Allahu pa okan won po mora won. Ti o ba je pe o na gbogbo nnkan ti n be lori ile patapata, iwo ko le pa okan won po mora won. Sugbon Allahu pa okan won po mora won, dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَسْبُكَ اللَّهُ وَمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Iwo Anabi, Allahu ti to iwo ati awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ حَرِّضِ الْمُؤْمِنِينَ عَلَى الْقِتَالِ ۚ إِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ عِشْرُونَ صَابِرُونَ يَغْلِبُوا مِائَتَيْنِ ۚ وَإِنْ يَكُنْ مِنْكُمْ مِائَةٌ يَغْلِبُوا أَلْفًا مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَفْقَهُونَ
Iwo Anabi, gba awon onigbagbo ododo ni iyanju lori ogun esin. Ti ogun onisuuru ba wa ninu yin, won yoo bori igba. Ti ogorun-un ba si wa ninu yin, won yoo bori egberun ninu awon t’o sai gbagbo nitori pe dajudaju won je ijo ti ko gbo agboye

Choose other languages: