Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #85 Translated in Yoruba

وَكَيْفَ أَخَافُ مَا أَشْرَكْتُمْ وَلَا تَخَافُونَ أَنَّكُمْ أَشْرَكْتُمْ بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ عَلَيْكُمْ سُلْطَانًا ۚ فَأَيُّ الْفَرِيقَيْنِ أَحَقُّ بِالْأَمْنِ ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ
Bawo ni emi yoo se paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Allahu, ti eyin ko si paya pe e n ba Allahu wa akegbe pelu ohun ti ko so eri kan kale fun yin lori re? Ewo ninu iko mejeeji l’o letoo julo si ifokanbale ti e ba nimo
الَّذِينَ آمَنُوا وَلَمْ يَلْبِسُوا إِيمَانَهُمْ بِظُلْمٍ أُولَٰئِكَ لَهُمُ الْأَمْنُ وَهُمْ مُهْتَدُونَ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won ko si da igbagbo won po mo abosi (iborisa), awon wonyen ni ifokanbale n be fun. Awon si ni olumona
وَتِلْكَ حُجَّتُنَا آتَيْنَاهَا إِبْرَاهِيمَ عَلَىٰ قَوْمِهِ ۚ نَرْفَعُ دَرَجَاتٍ مَنْ نَشَاءُ ۗ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٌ
Iyen ni awijare Wa ti A fun (Anabi) ’Ibrohim lori awon eniyan re. A n se agbega ipo fun eni ti A ba fe. Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo
وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۚ كُلًّا هَدَيْنَا ۚ وَنُوحًا هَدَيْنَا مِنْ قَبْلُ ۖ وَمِنْ ذُرِّيَّتِهِ دَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ وَأَيُّوبَ وَيُوسُفَ وَمُوسَىٰ وَهَارُونَ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Ati pe A ta a lore (Anabi) ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (ti o je omo ’Ishaƙ). Ikookan won ni A fi mona. A si fi (Anabi) Nuh mona siwaju. Ati pe ninu aromodomo (Anabi ’Ibrohim ti A fi mona ni awon Anabi) Dawud, Sulaemon, ’Ayyub, Yusuf, Musa ati Harun. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
وَزَكَرِيَّا وَيَحْيَىٰ وَعِيسَىٰ وَإِلْيَاسَ ۖ كُلٌّ مِنَ الصَّالِحِينَ
Ati (Anabi) Zakariyya, Yahya, ‘Isa ati ’Ilyas; gbogbo won wa ninu awon eni rere

Choose other languages: