Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #79 Translated in Yoruba

وَكَذَٰلِكَ نُرِي إِبْرَاهِيمَ مَلَكُوتَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلِيَكُونَ مِنَ الْمُوقِنِينَ
Bayen ni won se fi (awon ami) ijoba Allahu ti n be ninu awon sanmo ati ile han (Anabi) ’Ibrohim nitori ki o le wa ninu awon alamodaju
فَلَمَّا جَنَّ عَلَيْهِ اللَّيْلُ رَأَىٰ كَوْكَبًا ۖ قَالَ هَٰذَا رَبِّي ۖ فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لَا أُحِبُّ الْآفِلِينَ
Nigba ti okunkun ale bo o mole, o ri irawo kan, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Emi ko nifee si awon (oluwa) t’o n wookun.”
فَلَمَّا رَأَى الْقَمَرَ بَازِغًا قَالَ هَٰذَا رَبِّي ۖ فَلَمَّا أَفَلَ قَالَ لَئِنْ لَمْ يَهْدِنِي رَبِّي لَأَكُونَنَّ مِنَ الْقَوْمِ الضَّالِّينَ
Nigba ti o ri osupa t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Dajudaju ti Oluwa mi ko ba to mi sona, dajudaju mo maa wa ninu awon olusina eniyan.”
فَلَمَّا رَأَى الشَّمْسَ بَازِغَةً قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَا أَكْبَرُ ۖ فَلَمَّا أَفَلَتْ قَالَ يَا قَوْمِ إِنِّي بَرِيءٌ مِمَّا تُشْرِكُونَ
Nigba ti o ri oorun t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi; eyi tobi julo.” Nigba t’o wo, o so pe: “Eyin eniyan mi, dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu)
إِنِّي وَجَّهْتُ وَجْهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ حَنِيفًا ۖ وَمَا أَنَا مِنَ الْمُشْرِكِينَ
Dajudaju emi doju mi ko Eni ti O pile iseda awon sanmo ati ile, (mo) duro deede (sinu ’Islam fun Un). Emi ko si si ninu awon osebo.”

Choose other languages: