Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #71 Translated in Yoruba

لِكُلِّ نَبَإٍ مُسْتَقَرٌّ ۚ وَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
Gbogbo asotele l’o ni akoko (isele). Laipe e maa mo
وَإِذَا رَأَيْتَ الَّذِينَ يَخُوضُونَ فِي آيَاتِنَا فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ حَتَّىٰ يَخُوضُوا فِي حَدِيثٍ غَيْرِهِ ۚ وَإِمَّا يُنْسِيَنَّكَ الشَّيْطَانُ فَلَا تَقْعُدْ بَعْدَ الذِّكْرَىٰ مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Nigba ti o ba ri awon t’o n so isokuso nipa awon ayah Wa, nigba naa seri kuro ni odo won titi won yoo fi bo sinu oro miiran. Ti Esu ba n mu o gbagbe (tele), ni bayii leyin iranti ma se jokoo ti ijo alabosi
وَمَا عَلَى الَّذِينَ يَتَّقُونَ مِنْ حِسَابِهِمْ مِنْ شَيْءٍ وَلَٰكِنْ ذِكْرَىٰ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
Kini kan ninu isiro-ise won ko si lorun awon t’o n beru (Allahu), sugbon isiti ni nitori ki won le sora (fun Ina)
وَذَرِ الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَهُمْ لَعِبًا وَلَهْوًا وَغَرَّتْهُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۚ وَذَكِّرْ بِهِ أَنْ تُبْسَلَ نَفْسٌ بِمَا كَسَبَتْ لَيْسَ لَهَا مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلِيٌّ وَلَا شَفِيعٌ وَإِنْ تَعْدِلْ كُلَّ عَدْلٍ لَا يُؤْخَذْ مِنْهَا ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ أُبْسِلُوا بِمَا كَسَبُوا ۖ لَهُمْ شَرَابٌ مِنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Pa awon t’o so esin won di ere sise ati iranu ti. Isemi aye si tan won je. Fi (al-Ƙur’an) se isiti nitori ki won ma baa fa emi kale sinu iparun nipase ohun ti o se nise (aburu). Ko si si alaabo tabi olusipe kan fun un leyin Allahu. Ti o ba si fi gbogbo aaro serapada, A o nii gba a lowo re. Awon wonyen ni awon ti won fa kale fun iparun nipase ohun ti won se nise. Ohun mimu gbigbona ati iya eleta elero n be fun won nitori pe won maa n sai gbagbo
قُلْ أَنَدْعُو مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنْفَعُنَا وَلَا يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَىٰ أَعْقَابِنَا بَعْدَ إِذْ هَدَانَا اللَّهُ كَالَّذِي اسْتَهْوَتْهُ الشَّيَاطِينُ فِي الْأَرْضِ حَيْرَانَ لَهُ أَصْحَابٌ يَدْعُونَهُ إِلَى الْهُدَى ائْتِنَا ۗ قُلْ إِنَّ هُدَى اللَّهِ هُوَ الْهُدَىٰ ۖ وَأُمِرْنَا لِنُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ
So pe: “Se a oo maa pe leyin Allahu, ohun ti ko le se wa ni anfaani, ti ko si le ko inira ba wa; (se) ki won tun da wa pada si ese-aaro wa leyin igba ti Allahu ti fi ona mo wa (ki a le da) bi eni ti Esu mu tele ife-inu re lori ile aye, ti idaamu de ba? O (si) ni awon ore kan ti won n pe e sibi imona (pe), “Maa bo ni odo wa.” So pe: “Dajudaju imona ti Allahu (’Islam), ohun ni imona. Won si pa wa lase pe ki a gba esin ’Islam nitori ti Oluwa gbogbo eda.”

Choose other languages: