Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #136 Translated in Yoruba

وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِمَّا عَمِلُوا ۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ
Awon ipo (ike ati ipo iya) n be fun enikookan nipase ohun ti won ba se nise. Oluwa re ki i se onigbagbe nipa nnkan ti won n se nise
وَرَبُّكَ الْغَنِيُّ ذُو الرَّحْمَةِ ۚ إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ وَيَسْتَخْلِفْ مِنْ بَعْدِكُمْ مَا يَشَاءُ كَمَا أَنْشَأَكُمْ مِنْ ذُرِّيَّةِ قَوْمٍ آخَرِينَ
Oluwa re ni Oloro, Alaaanu. Ti O ba fe, O maa ko yin kuro (lori ile). O si maa fi ohun ti O ba fe ropo (yin) leyin (iparun) yin gege bi O ti se mu yin jade leyin (iparun) aromodomo awon ijo miiran
إِنَّ مَا تُوعَدُونَ لَآتٍ ۖ وَمَا أَنْتُمْ بِمُعْجِزِينَ
Dajudaju ohun ti A n se ni adehun fun yin, o kuku n bo wa sele; eyin ko si nii mori bo
قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ مَنْ تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۗ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
So pe: “Eyin eniyan mi, e duro sori ona yin, dajudaju emi naa yoo duro (sori ona mi), laipe e maa mo eni ti Ogba (Idera) yoo je ikangun tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”
وَجَعَلُوا لِلَّهِ مِمَّا ذَرَأَ مِنَ الْحَرْثِ وَالْأَنْعَامِ نَصِيبًا فَقَالُوا هَٰذَا لِلَّهِ بِزَعْمِهِمْ وَهَٰذَا لِشُرَكَائِنَا ۖ فَمَا كَانَ لِشُرَكَائِهِمْ فَلَا يَصِلُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَمَا كَانَ لِلَّهِ فَهُوَ يَصِلُ إِلَىٰ شُرَكَائِهِمْ ۗ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ
Won si fi ipin kan fun Allahu ninu ohun ti O da ninu nnkan oko ati eran-osin; won wi pe: "Eyi ni ti Allahu – pelu oro won lai ni eri lowo, - eyi si ni ti awon orisa wa." Nitori naa, ohun ti o ba je ti awon orisa ko nii dapo mo ti Allahu. Ohun ti o ba si je ti Allahu, o n dapo mo ti awon orisa won; ohun ti won n da lejo buru

Choose other languages: