Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #25 Translated in Yoruba

لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِي رَسُولِ اللَّهِ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِمَنْ كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ وَذَكَرَ اللَّهَ كَثِيرًا
Dajudaju awokose rere wa fun yin lara Ojise Allahu fun enikeni ti o ba n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si ranti Allahu ni opolopo (igba)
وَلَمَّا رَأَى الْمُؤْمِنُونَ الْأَحْزَابَ قَالُوا هَٰذَا مَا وَعَدَنَا اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَصَدَقَ اللَّهُ وَرَسُولُهُ ۚ وَمَا زَادَهُمْ إِلَّا إِيمَانًا وَتَسْلِيمًا
Nigba ti awon onigbagbo ododo ri awon omo ogun onijo, won so pe: “Eyi ni ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni adehun fun wa. Allahu ati Ojise Re ti so ododo oro.” (Riri won) ko se alekun kan fun won bi ko se (alekun) igbagbo ododo ati ijuwo-juse-sile (fun ase Allahu)
مِنَ الْمُؤْمِنِينَ رِجَالٌ صَدَقُوا مَا عَاهَدُوا اللَّهَ عَلَيْهِ ۖ فَمِنْهُمْ مَنْ قَضَىٰ نَحْبَهُ وَمِنْهُمْ مَنْ يَنْتَظِرُ ۖ وَمَا بَدَّلُوا تَبْدِيلًا
O wa ninu awon onigbagbo ododo, awon okunrin kan ti won je olododo nipa adehun ti won ba Allahu se; o wa ninu won eni ti o pe adehun re (t’o si ku soju ogun esin), o si wa ninu won eni t’o n reti (iku tire). Won ko si yi (adehun) pada rara
لِيَجْزِيَ اللَّهُ الصَّادِقِينَ بِصِدْقِهِمْ وَيُعَذِّبَ الْمُنَافِقِينَ إِنْ شَاءَ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَحِيمًا
(Iwonyi ri bee) nitori ki Allahu le fi (ododo) awon olododo san won ni esan ododo won, ati nitori ki O le je awon sobe-selu musulumi ni iya ti O ba fe tabi nitori ki O le gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun
وَرَدَّ اللَّهُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِغَيْظِهِمْ لَمْ يَنَالُوا خَيْرًا ۚ وَكَفَى اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ الْقِتَالَ ۚ وَكَانَ اللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزًا
Allahu si da awon t’o sai gbagbo pada tohun ti ibinu won; owo won ko si te oore kan. Allahu si to awon onigbagbo ododo nibi ogun naa. Allahu si n je Alagbara, Olubori

Choose other languages: