Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #27 Translated in Yoruba

مِنَ الْمُؤْمِنِينَ رِجَالٌ صَدَقُوا مَا عَاهَدُوا اللَّهَ عَلَيْهِ ۖ فَمِنْهُمْ مَنْ قَضَىٰ نَحْبَهُ وَمِنْهُمْ مَنْ يَنْتَظِرُ ۖ وَمَا بَدَّلُوا تَبْدِيلًا
O wa ninu awon onigbagbo ododo, awon okunrin kan ti won je olododo nipa adehun ti won ba Allahu se; o wa ninu won eni ti o pe adehun re (t’o si ku soju ogun esin), o si wa ninu won eni t’o n reti (iku tire). Won ko si yi (adehun) pada rara
لِيَجْزِيَ اللَّهُ الصَّادِقِينَ بِصِدْقِهِمْ وَيُعَذِّبَ الْمُنَافِقِينَ إِنْ شَاءَ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَحِيمًا
(Iwonyi ri bee) nitori ki Allahu le fi (ododo) awon olododo san won ni esan ododo won, ati nitori ki O le je awon sobe-selu musulumi ni iya ti O ba fe tabi nitori ki O le gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun
وَرَدَّ اللَّهُ الَّذِينَ كَفَرُوا بِغَيْظِهِمْ لَمْ يَنَالُوا خَيْرًا ۚ وَكَفَى اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ الْقِتَالَ ۚ وَكَانَ اللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزًا
Allahu si da awon t’o sai gbagbo pada tohun ti ibinu won; owo won ko si te oore kan. Allahu si to awon onigbagbo ododo nibi ogun naa. Allahu si n je Alagbara, Olubori
وَأَنْزَلَ الَّذِينَ ظَاهَرُوهُمْ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مِنْ صَيَاصِيهِمْ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ الرُّعْبَ فَرِيقًا تَقْتُلُونَ وَتَأْسِرُونَ فَرِيقًا
(Allahu) si mu awon t’o seranlowo fun (awon omo ogun onijo) ninu awon ahlul-kitab sokale kuro ninu awon odi won. O si ju eru sinu okan won. E n pa igun kan (ninu won), e si n ko igun kan leru
وَأَوْرَثَكُمْ أَرْضَهُمْ وَدِيَارَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ وَأَرْضًا لَمْ تَطَئُوهَا ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرًا
(Allahu) si jogun ile won, ile won, dukia won ati ile ti e o te ri fun yin. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

Choose other languages: