Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #11 Translated in Yoruba

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yo si maa so isokuso si ododo nigba ti o de ba won pe: "Eyi ni idan ponnbele
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَلَا تَمْلِكُونَ لِي مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِ ۖ كَفَىٰ بِهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۖ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." So pe: "Ti mo ba hun un funra mi, e o ni ikapa kini kan fun mi ni odo Allahu (nibi iya Re). Oun ni Onimo-julo nipa isokuso ti e n so nipa re. O (si) to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Oun ni Alaforijin, Asake-orun
قُلْ مَا كُنْتُ بِدْعًا مِنَ الرُّسُلِ وَمَا أَدْرِي مَا يُفْعَلُ بِي وَلَا بِكُمْ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ وَمَا أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُبِينٌ
So pe: "Emi ki i se akoko ninu awon Ojise. Emi ko si mo nnkan ti won maa se fun emi ati eyin. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele." won wa labe ijoba awon osebo ninu ilu Mokkah alapon-onle. Won si bere si nii yowo kowo si awon omoleyin Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Lasiko naa ipo ole ni awon musulumi wa ninu ilu naa. Ko si ohun t’o wa le fi won lokan bale sinu ’Islam tayo ki Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) je ki o di mimo fun eni kookan awon omoleyin re pe ijiya ati pipa han awon musulumi ni eemo ifoju-egbo-rin. Mo daju pe ko si Anabi kan ninu awon Anabi Olohun (ahm.s.w.) ti ko mo pe ti o ba je pe itumo ti awon kristieni fun ayah naa l’o ba je ododo “emi ko si mo nnkan ti Allahu maa se fun emi ati eyin” ni iba je agbekale re. Bakan naa ise ti Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) je faye ko yato si ti awon t’o siwaju re ninu awon Ojise Allahu (ahm.s.w). Bakan naa ayah naa n pe wa sibi iduro sinsin ati atemora lasiko inira awon alaigbagbo
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كَانَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَكَفَرْتُمْ بِهِ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ مِثْلِهِ فَآمَنَ وَاسْتَكْبَرْتُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe lati odo Allahu ni (al-Ƙur’an) ti wa, ti e si sai gbagbo ninu re, ti elerii kan ninu awon omo ’Isro’il si jerii lori iru re, ti o si gba a gbo, (amo) ti eyin segberaga si i, (se e o ti sabosi bayen bi?). Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا لَوْ كَانَ خَيْرًا مَا سَبَقُونَا إِلَيْهِ ۚ وَإِذْ لَمْ يَهْتَدُوا بِهِ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَا إِفْكٌ قَدِيمٌ
Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Ti o ba je pe al-Ƙur’an je oore ni, won ko nii siwaju wa debe." Nigba ti awon osebo ko ti tele imona re, ni won n wi pe: "Iro ijoun ni eyi

Choose other languages: