Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #30 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ مَكَّنَّاهُمْ فِيمَا إِنْ مَكَّنَّاكُمْ فِيهِ وَجَعَلْنَا لَهُمْ سَمْعًا وَأَبْصَارًا وَأَفْئِدَةً فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ سَمْعُهُمْ وَلَا أَبْصَارُهُمْ وَلَا أَفْئِدَتُهُمْ مِنْ شَيْءٍ إِذْ كَانُوا يَجْحَدُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
A kuku fun won ni ipo ti A o fun eyin. A si fun won ni igboro, awon iriran ati awon okan. Amo igboro won ati awon iriran won pelu awon okan won ko ro won loro kan kan nibi iya nitori pe won n se atako si awon ayah Allahu. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا مَا حَوْلَكُمْ مِنَ الْقُرَىٰ وَصَرَّفْنَا الْآيَاتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Awa kuku ti pa re ninu awon ilu ti o wa ni ayika yin. Awa si ti salaye awon ayah naa ni orisirisi ona nitori ki won le seri pada (sibi ododo)
فَلَوْلَا نَصَرَهُمُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِ اللَّهِ قُرْبَانًا آلِهَةً ۖ بَلْ ضَلُّوا عَنْهُمْ ۚ وَذَٰلِكَ إِفْكُهُمْ وَمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Awon olohun ti won so di ohun ti o maa mu won sunmo (igbala) leyin Allahu ko se ran won lowo mo? Rara (ko le si aranse fun won)! Won ti dofo mo won lowo. Iyen si ni (olohun) iro won ati ohun ti won n da ni adapa iro
وَإِذْ صَرَفْنَا إِلَيْكَ نَفَرًا مِنَ الْجِنِّ يَسْتَمِعُونَ الْقُرْآنَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوا أَنْصِتُوا ۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوْا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ مُنْذِرِينَ
(Ranti) nigba ti A dari ijo kan ninu awon alujannu si o, ti won n teti gbo al-Ƙur’an. Nigba ti won de sibe, won so pe: "E dake (fun al-Ƙur’an)." Nigba ti won si pari (kike re tan), won pada si odo ijo won, ti won n sekilo (fun won)
قَالُوا يَا قَوْمَنَا إِنَّا سَمِعْنَا كِتَابًا أُنْزِلَ مِنْ بَعْدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٍ مُسْتَقِيمٍ
Won so pe: "Eyin ijo wa, dajudaju awa gbo (nipa) Tira kan ti won sokale leyin (Anabi) Musa, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re, ti o si n toni si ona ododo ati ona taara

Choose other languages: