Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #81 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ يَشْتَرُونَ بِعَهْدِ اللَّهِ وَأَيْمَانِهِمْ ثَمَنًا قَلِيلًا أُولَٰئِكَ لَا خَلَاقَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ اللَّهُ وَلَا يَنْظُرُ إِلَيْهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dajudaju awon t’o n ta majemu Allahu ati ibura won ni owo kekere, awon wonyen, ko nii si ipin oore fun won ni Ojo Ikeyin. Allahu ko nii ba won soro, ko si nii siju wo won ni Ojo Ajinde. Ko si nii fo won mo (ninu ese) Iya eleta-elero si n be fun won
وَإِنَّ مِنْهُمْ لَفَرِيقًا يَلْوُونَ أَلْسِنَتَهُمْ بِالْكِتَابِ لِتَحْسَبُوهُ مِنَ الْكِتَابِ وَمَا هُوَ مِنَ الْكِتَابِ وَيَقُولُونَ هُوَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَمَا هُوَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَيَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Dajudaju ijo kan n be ninu won t’o n fi ahon won yi tira (Allahu) pada, nitori ki e le lero pe lara tira lo wa, ko si si lara tira. Won si n wi pe: “O wa lati odo Allahu.” Ko si wa lati odo Allahu. Won n paro mo Allahu, won si mo
مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَنْ يُؤْتِيَهُ اللَّهُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُوا عِبَادًا لِي مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلَٰكِنْ كُونُوا رَبَّانِيِّينَ بِمَا كُنْتُمْ تُعَلِّمُونَ الْكِتَابَ وَبِمَا كُنْتُمْ تَدْرُسُونَ
Ko letoo fun abara kan nigba ti Allahu ba fun un ni tira, ijinle oye ati ipo Anabi, leyin naa ki o maa so fun awon eniyan pe, "e je erusin fun mi leyin Allahu." Sugbon (o maa so pe) "e je olujosin fun Oluwa (ki e si maa fi eko Re ko awon eniyan) nitori pe e je eni ti n ko awon eniyan ni tira ati nitori pe e je eni ti n ko eko (nipa esin)
وَلَا يَأْمُرَكُمْ أَنْ تَتَّخِذُوا الْمَلَائِكَةَ وَالنَّبِيِّينَ أَرْبَابًا ۗ أَيَأْمُرُكُمْ بِالْكُفْرِ بَعْدَ إِذْ أَنْتُمْ مُسْلِمُونَ
(Anabi kan) ko si nii pa yin ni ase pe ki e so awon molaika ati awon Anabi di oluwa. Se o maa pa yin ni ase sise aigbagbo leyin ti e ti je musulumi ni
وَإِذْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ النَّبِيِّينَ لَمَا آتَيْتُكُمْ مِنْ كِتَابٍ وَحِكْمَةٍ ثُمَّ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مُصَدِّقٌ لِمَا مَعَكُمْ لَتُؤْمِنُنَّ بِهِ وَلَتَنْصُرُنَّهُ ۚ قَالَ أَأَقْرَرْتُمْ وَأَخَذْتُمْ عَلَىٰ ذَٰلِكُمْ إِصْرِي ۖ قَالُوا أَقْرَرْنَا ۚ قَالَ فَاشْهَدُوا وَأَنَا مَعَكُمْ مِنَ الشَّاهِدِينَ
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun lowo awon Anabi pe: “(E lo) eyi ti Mo ba fun yin ninu Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah eni kookan won). Leyin naa, Ojise kan (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) yoo de ba yin; o maa fi eyi t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. Nitori naa, e gbodo gba a gbo, e si gbodo ran an lowo.” (Allahu) so pe: “Nje e gba? Se e si maa lo adehun Mi yii?” Won so pe: “A gba.” (Allahu) so pe: "Nitori naa, e jerii si (adehun naa). Emi n be pelu yin ninu awon Olujerii

Choose other languages: