Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #78 Translated in Yoruba

يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِ مَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ
(Allahu) n sa eni ti O ba fe lesa. Allahu ni Oloore nla
وَمِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مَنْ إِنْ تَأْمَنْهُ بِقِنْطَارٍ يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ وَمِنْهُمْ مَنْ إِنْ تَأْمَنْهُ بِدِينَارٍ لَا يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ إِلَّا مَا دُمْتَ عَلَيْهِ قَائِمًا ۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لَيْسَ عَلَيْنَا فِي الْأُمِّيِّينَ سَبِيلٌ وَيَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
O n be ninu awon ahlul-kitab, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu opolopo owo, o maa da a pada fun o. O si n be ninu won, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu owo dinar kan (owo kekere), ko nii da a pada fun o ayafi ti o ba dogo ti i lorun. Iyen nitori pe won wi pe: “Won ko le fi ona kan kan ba wa wi nitori awon alaimoonkomoonka.” Nse ni won n pa iro mo Allahu, won si mo
بَلَىٰ مَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ وَاتَّقَىٰ فَإِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Rara (A maa ba won wi). Enikeni ti o ba mu adehun re se, ti o si beru (Allahu), dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)
إِنَّ الَّذِينَ يَشْتَرُونَ بِعَهْدِ اللَّهِ وَأَيْمَانِهِمْ ثَمَنًا قَلِيلًا أُولَٰئِكَ لَا خَلَاقَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ اللَّهُ وَلَا يَنْظُرُ إِلَيْهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dajudaju awon t’o n ta majemu Allahu ati ibura won ni owo kekere, awon wonyen, ko nii si ipin oore fun won ni Ojo Ikeyin. Allahu ko nii ba won soro, ko si nii siju wo won ni Ojo Ajinde. Ko si nii fo won mo (ninu ese) Iya eleta-elero si n be fun won
وَإِنَّ مِنْهُمْ لَفَرِيقًا يَلْوُونَ أَلْسِنَتَهُمْ بِالْكِتَابِ لِتَحْسَبُوهُ مِنَ الْكِتَابِ وَمَا هُوَ مِنَ الْكِتَابِ وَيَقُولُونَ هُوَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَمَا هُوَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَيَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Dajudaju ijo kan n be ninu won t’o n fi ahon won yi tira (Allahu) pada, nitori ki e le lero pe lara tira lo wa, ko si si lara tira. Won si n wi pe: “O wa lati odo Allahu.” Ko si wa lati odo Allahu. Won n paro mo Allahu, won si mo

Choose other languages: