Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #61 Translated in Yoruba

وَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الظَّالِمِينَ
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (Allahu) maa fun won ni esan won ni kikun. Allahu ko si feran awon alabosi
ذَٰلِكَ نَتْلُوهُ عَلَيْكَ مِنَ الْآيَاتِ وَالذِّكْرِ الْحَكِيمِ
Iyen ni A n ke fun o ninu awon ayah ati iranti ti o kun fun ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an)
إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِنْدَ اللَّهِ كَمَثَلِ آدَمَ ۖ خَلَقَهُ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ قَالَ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ
Dajudaju iru ‘Isa lodo Allahu da bi iru Adam; (Allahu) da a lati ara erupe. Leyin naa, O so pe: “Je bee.” O si je bee. eru Olohun ati Anabi Olohun. Amo siso ti awon kristieni so Anabi ‘Isa (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) di oluwa won olugbala won
الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ فَلَا تَكُنْ مِنَ الْمُمْتَرِينَ
Ododo ni lati odo Oluwa re. Nitori naa, ma se wa ninu awon oniyemeji
فَمَنْ حَاجَّكَ فِيهِ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ فَقُلْ تَعَالَوْا نَدْعُ أَبْنَاءَنَا وَأَبْنَاءَكُمْ وَنِسَاءَنَا وَنِسَاءَكُمْ وَأَنْفُسَنَا وَأَنْفُسَكُمْ ثُمَّ نَبْتَهِلْ فَنَجْعَلْ لَعْنَتَ اللَّهِ عَلَى الْكَاذِبِينَ
Nitori naa, enikeni ti o ba ja o niyan nipa re leyin ohun ti o de ba o ninu imo, ki o so pe: “E wa! Ki a pe awon omokunrin wa ati awon omokunrin yin ati awon obinrin wa ati awon obinrin yin ati awa ati eyin naa. Leyin naa, ki a se adua taratara, ki a si toro egun Allahu le awon opuro lori.”

Choose other languages: