Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #64 Translated in Yoruba

الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ فَلَا تَكُنْ مِنَ الْمُمْتَرِينَ
Ododo ni lati odo Oluwa re. Nitori naa, ma se wa ninu awon oniyemeji
فَمَنْ حَاجَّكَ فِيهِ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ فَقُلْ تَعَالَوْا نَدْعُ أَبْنَاءَنَا وَأَبْنَاءَكُمْ وَنِسَاءَنَا وَنِسَاءَكُمْ وَأَنْفُسَنَا وَأَنْفُسَكُمْ ثُمَّ نَبْتَهِلْ فَنَجْعَلْ لَعْنَتَ اللَّهِ عَلَى الْكَاذِبِينَ
Nitori naa, enikeni ti o ba ja o niyan nipa re leyin ohun ti o de ba o ninu imo, ki o so pe: “E wa! Ki a pe awon omokunrin wa ati awon omokunrin yin ati awon obinrin wa ati awon obinrin yin ati awa ati eyin naa. Leyin naa, ki a se adua taratara, ki a si toro egun Allahu le awon opuro lori.”
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْقَصَصُ الْحَقُّ ۚ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا اللَّهُ ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Dajudaju eyi, ohun ni itan ododo. Ati pe ko si olohun kan ti ijosin to si afi Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Ologbon
فَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِالْمُفْسِدِينَ
Ti won ba si peyin da (nibi ododo naa), dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon obileje
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَىٰ كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللَّهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِنْ دُونِ اللَّهِ ۚ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ
So pe: “Eyin ahlu-l-kitab, e wa sibi oro kan t’o dogba laaarin awa ati eyin, pe a o nii josin fun eni kan afi Allahu. A o si nii fi kini kan wa akegbe fun Un. Ati pe apa kan wa ko nii so apa kan di oluwa leyin Allahu.” Ti won ba si gbunri, e so pe: “E jerii pe dajudaju musulumi ni awa.”

Choose other languages: