Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #18 Translated in Yoruba

زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاءِ وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ الْمُقَنْطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ وَالْأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ۗ ذَٰلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَاللَّهُ عِنْدَهُ حُسْنُ الْمَآبِ
Won se e ni oso fun awon eniyan; ife igbadun lara awon obinrin, awon omokunrin, awon owo wura ati fadaka pupo ati awon esin ti won se ni oso, awon eran-osin ati (nnkan) oko. Iyen ni nnkan igbaye-gbadun. Odo Allahu si ni abo rere wa
قُلْ أَؤُنَبِّئُكُمْ بِخَيْرٍ مِنْ ذَٰلِكُمْ ۚ لِلَّذِينَ اتَّقَوْا عِنْدَ رَبِّهِمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَأَزْوَاجٌ مُطَهَّرَةٌ وَرِضْوَانٌ مِنَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِالْعِبَادِ
So pe: “Se ki ng so nnkan t’o dara ju iyen lo fun yin?” Awon t’o ba beru (Allahu), awon Ogba ti awon odo n san ni isale re n be fun won ni odo Oluwa won. Olusegbere ni won ninu re. Awon iyawo mimo ati iyonu lati odo Allahu (tun n be fun won). Allahu si ni Oluriran nipa awon erusin
الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا إِنَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
awon t’o n so pe: "Oluwa wa, dajudaju awa gbagbo. Nitori naa, fori awon ese wa jin wa. Ki O si so wa nibi iya Ina
الصَّابِرِينَ وَالصَّادِقِينَ وَالْقَانِتِينَ وَالْمُنْفِقِينَ وَالْمُسْتَغْفِرِينَ بِالْأَسْحَارِ
(Ogba Idera yen wa fun) awon onisuuru, awon olododo, awon olutele-ase Allahu, awon olunawo-fesin ati awon olutoro-aforijin ni asiko saari
شَهِدَ اللَّهُ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَالْمَلَائِكَةُ وَأُولُو الْعِلْمِ قَائِمًا بِالْقِسْطِ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Allahu jerii pe dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Awon molaika ati onimo esin (tun jerii bee.), Allahu ni Onideede. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara, Ologbon

Choose other languages: