Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #98 Translated in Yoruba

وَلَمَّا فَصَلَتِ الْعِيرُ قَالَ أَبُوهُمْ إِنِّي لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَ ۖ لَوْلَا أَنْ تُفَنِّدُونِ
Nigba ti ero-rakunmi naa si pinya (kuro lodo Anabi Yusuf), baba won so pe: “Dajudaju emi n gbo oorun Yusuf ti e o ba nii so pe mo n jaran.”
قَالُوا تَاللَّهِ إِنَّكَ لَفِي ضَلَالِكَ الْقَدِيمِ
Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju iwo si wa ninu asise re ti atijo (nipa ife Yusuf).”
فَلَمَّا أَنْ جَاءَ الْبَشِيرُ أَلْقَاهُ عَلَىٰ وَجْهِهِ فَارْتَدَّ بَصِيرًا ۖ قَالَ أَلَمْ أَقُلْ لَكُمْ إِنِّي أَعْلَمُ مِنَ اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Nigba ti oniroo-idunnu de, o ju (ewu naa) le e niwaju, o si riran pada. O so pe: “Nje ng ko so fun yin pe dajudaju emi mo ohun ti e ko mo nipa Allahu.”
قَالُوا يَا أَبَانَا اسْتَغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا إِنَّا كُنَّا خَاطِئِينَ
Won so pe: “Baba wa, toro aforijin ese wa fun wa, dajudaju awa je alasise.”
قَالَ سَوْفَ أَسْتَغْفِرُ لَكُمْ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
O so pe: “Laipe mo maa toro aforijin fun yin lodo Oluwa mi. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun.”

Choose other languages: