Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #36 Translated in Yoruba

قَالَتْ فَذَٰلِكُنَّ الَّذِي لُمْتُنَّنِي فِيهِ ۖ وَلَقَدْ رَاوَدْتُهُ عَنْ نَفْسِهِ فَاسْتَعْصَمَ ۖ وَلَئِنْ لَمْ يَفْعَلْ مَا آمُرُهُ لَيُسْجَنَنَّ وَلَيَكُونًا مِنَ الصَّاغِرِينَ
(Ayaba) so pe: “Iyen ni eni ti e bu mi fun. Dajudaju mo jireebe fun ere ife lodo re, o si wa isora. Dajudaju ti ko ba se ohun ti mo n pa lase fun un, won kuku maa fi sinu ogba ewon ni. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni yepere.”
قَالَ رَبِّ السِّجْنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدْعُونَنِي إِلَيْهِ ۖ وَإِلَّا تَصْرِفْ عَنِّي كَيْدَهُنَّ أَصْبُ إِلَيْهِنَّ وَأَكُنْ مِنَ الْجَاهِلِينَ
(Yusuf) so pe: “Oluwa (Eledaa) mi, ogba ewon ni mo nifee si ju ohun ti won n pe mi si. Ti O o ba si seri ete won kuro lodo mi, emi yoo ko sinu ete won, emi yo si wa lara awon alaimokan.”
فَاسْتَجَابَ لَهُ رَبُّهُ فَصَرَفَ عَنْهُ كَيْدَهُنَّ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Nitori naa, Oluwa re jepe re. O si seri ete won kuro lodo re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo
ثُمَّ بَدَا لَهُمْ مِنْ بَعْدِ مَا رَأَوُا الْآيَاتِ لَيَسْجُنُنَّهُ حَتَّىٰ حِينٍ
Leyin igba ti won ti ri awon ami (pe Yusuf ko jebi esun), leyin naa, o han si won pe awon gbodo so o sinu ogba ewon titi di asiko kan na
وَدَخَلَ مَعَهُ السِّجْنَ فَتَيَانِ ۖ قَالَ أَحَدُهُمَا إِنِّي أَرَانِي أَعْصِرُ خَمْرًا ۖ وَقَالَ الْآخَرُ إِنِّي أَرَانِي أَحْمِلُ فَوْقَ رَأْسِي خُبْزًا تَأْكُلُ الطَّيْرُ مِنْهُ ۖ نَبِّئْنَا بِتَأْوِيلِهِ ۖ إِنَّا نَرَاكَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ
Awon odokunrin meji kan wo inu ogba ewon pelu re. Okan ninu awon mejeeji so pe: “Emi lalaa ri ara mi pe mo n fun oti.” Eni keji so pe: “Dajudaju emi lalaa ri ara mi pe mo gbe buredi ru sori mi, eye si n je ninu re.” So itumo re fun wa. Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu awon eni rere

Choose other languages: