Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #105 Translated in Yoruba

رَبِّ قَدْ آتَيْتَنِي مِنَ الْمُلْكِ وَعَلَّمْتَنِي مِنْ تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ ۚ فَاطِرَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ أَنْتَ وَلِيِّي فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ تَوَفَّنِي مُسْلِمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ
Oluwa mi, dajudaju O ti fun mi ni ijoba. O tun fun mi ni imo itumo ala. Olupileda awon sanmo ati ile, Iwo ni Oluranlowo mi ni aye ati ni orun, pa mi sipo musulumi. Ki O si fi mi pelu awon eni rere.”
ذَٰلِكَ مِنْ أَنْبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۖ وَمَا كُنْتَ لَدَيْهِمْ إِذْ أَجْمَعُوا أَمْرَهُمْ وَهُمْ يَمْكُرُونَ
Iyen wa ninu iro ikoko ti A fi imisi (re) ranse si o. Ati pe iwo ko si lodo won nigba ti won panu po lori oro won, ti won n dete
وَمَا أَكْثَرُ النَّاسِ وَلَوْ حَرَصْتَ بِمُؤْمِنِينَ
Iwo ibaa soju kokoro (igbala won), opolopo eniyan ni ko nii gbagbo
وَمَا تَسْأَلُهُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِلْعَالَمِينَ
Iwo ko si bi won leere owo-oya kan lori re. Ko si je kini kan bi ko se iranti fun gbogbo eda
وَكَأَيِّنْ مِنْ آيَةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ يَمُرُّونَ عَلَيْهَا وَهُمْ عَنْهَا مُعْرِضُونَ
Ati pe meloo meloo ninu awon ami ti n be ni sanmo ati ni ori ile ti won n re koja lori re, ti won si n gbunri kuro nibe

Choose other languages: