Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #64 Translated in Yoruba

وَمَا ظَنُّ الَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَشْكُرُونَ
Ki ni ero-okan awon t’o n da adapa iro mo Allahu ni Ojo Ajinde na? Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo won ni ki i dupe (fun Un)
وَمَا تَكُونُ فِي شَأْنٍ وَمَا تَتْلُو مِنْهُ مِنْ قُرْآنٍ وَلَا تَعْمَلُونَ مِنْ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيْكُمْ شُهُودًا إِذْ تُفِيضُونَ فِيهِ ۚ وَمَا يَعْزُبُ عَنْ رَبِّكَ مِنْ مِثْقَالِ ذَرَّةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ وَلَا أَصْغَرَ مِنْ ذَٰلِكَ وَلَا أَكْبَرَ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُبِينٍ
Iwo ko nii wa ninu ise kan, iwo ko si nii ke (ayah kan) ninu al-Ƙur’an, eyin ko nii se ise kan afi ki Awa je Elerii lori yin nigba ti e ba n se e. Kini kan ko pamo fun Oluwa re; ti o mo ni odiwon ina-igun ninu ile ati ninu sanmo, ki o tun kere ju iyen lo tabi ki o tobi ju u lo afi ki o wa ninu akosile t’o yanju
أَلَا إِنَّ أَوْلِيَاءَ اللَّهِ لَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Gbo, dajudaju awon ore Allahu, ko nii si iberu (iya orun) fun won, won ko si nii banuje (lori oore aye)
الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ
(Awon ni) awon t’o gbagbo lododo, won si maa n beru (Allahu)
لَهُمُ الْبُشْرَىٰ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۚ لَا تَبْدِيلَ لِكَلِمَاتِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Ti won ni iro idunnu ninu isemi aye (yii) ati ni Ojo Ikeyin. Ko si iyipada kan fun awon oro Allahu. Iyen, ohun ni erenje nla

Choose other languages: