Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #66 Translated in Yoruba

أَلَا إِنَّ أَوْلِيَاءَ اللَّهِ لَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Gbo, dajudaju awon ore Allahu, ko nii si iberu (iya orun) fun won, won ko si nii banuje (lori oore aye)
الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ
(Awon ni) awon t’o gbagbo lododo, won si maa n beru (Allahu)
لَهُمُ الْبُشْرَىٰ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۚ لَا تَبْدِيلَ لِكَلِمَاتِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Ti won ni iro idunnu ninu isemi aye (yii) ati ni Ojo Ikeyin. Ko si iyipada kan fun awon oro Allahu. Iyen, ohun ni erenje nla
وَلَا يَحْزُنْكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّ الْعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا ۚ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Ma se je ki oro (enu) won ba o ninu je. Dajudaju gbogbo agbara patapata n je ti Allahu. Oun ni Olugbo, Onimo
أَلَا إِنَّ لِلَّهِ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ ۗ وَمَا يَتَّبِعُ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ شُرَكَاءَ ۚ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Gbo, dajudaju ti Allahu ni enikeni t’o n be ninu awon sanmo ati enikeni t’o n be lori ile. Ki ni awon t’o n pe awon orisa leyin Allahu n tele na? Won ko tele (kini kan) bi ko se aroso. Won ko si se kini kan bi ko se pe won n paro

Choose other languages: