Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #8 Translated in Yoruba

إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ إِنَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ بِالْقِسْطِ ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ شَرَابٌ مِنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo
هُوَ الَّذِي جَعَلَ الشَّمْسَ ضِيَاءً وَالْقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُ مَنَازِلَ لِتَعْلَمُوا عَدَدَ السِّنِينَ وَالْحِسَابَ ۚ مَا خَلَقَ اللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِالْحَقِّ ۚ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo
إِنَّ فِي اخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَّقُونَ
Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu)
إِنَّ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا وَرَضُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاطْمَأَنُّوا بِهَا وَالَّذِينَ هُمْ عَنْ آيَاتِنَا غَافِلُونَ
Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa
أُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمُ النَّارُ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
awon wonyen, ibugbe won ni Ina nitori ohun ti won n se nise

Choose other languages: