Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #7 Translated in Yoruba

إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ ۖ مَا مِنْ شَفِيعٍ إِلَّا مِنْ بَعْدِ إِذْنِهِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n seto oro (eda). Ko si olusipe kan afi leyin iyonda Re. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Se e o nii lo iranti ni
إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ إِنَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ بِالْقِسْطِ ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ شَرَابٌ مِنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo
هُوَ الَّذِي جَعَلَ الشَّمْسَ ضِيَاءً وَالْقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُ مَنَازِلَ لِتَعْلَمُوا عَدَدَ السِّنِينَ وَالْحِسَابَ ۚ مَا خَلَقَ اللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِالْحَقِّ ۚ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo
إِنَّ فِي اخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَّقُونَ
Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu)
إِنَّ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا وَرَضُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاطْمَأَنُّوا بِهَا وَالَّذِينَ هُمْ عَنْ آيَاتِنَا غَافِلُونَ
Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa

Choose other languages: