Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #21 Translated in Yoruba

فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْمُجْرِمُونَ
Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon odaran ko nii jere
وَيَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمْ وَلَا يَنْفَعُهُمْ وَيَقُولُونَ هَٰؤُلَاءِ شُفَعَاؤُنَا عِنْدَ اللَّهِ ۚ قُلْ أَتُنَبِّئُونَ اللَّهَ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Won n josin fun ohun ti ko le ko inira ba won, ti ko si le se won ni anfaani leyin Allahu. Won si n wi pe: “Awon wonyi ni olusipe wa lodo Allahu.” So pe: “Se e maa fun Allahu ni iro ohun ti ko mo ninu awon sanmo ati ile ni?” Mimo ni fun Un, O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
وَمَا كَانَ النَّاسُ إِلَّا أُمَّةً وَاحِدَةً فَاخْتَلَفُوا ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Ki ni awon eniyan je (ni ipile) bi ko se ijo eyo kan (ijo ’Islam). Leyin naa ni won yapa enu. Ti ko ba je pe oro kan t’o ti siwaju lodo Oluwa re, Awa iba ti yanju ohun ti won n yapa enu si laaarin ara won
وَيَقُولُونَ لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۖ فَقُلْ إِنَّمَا الْغَيْبُ لِلَّهِ فَانْتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُنْتَظِرِينَ
Won n wi pe: “Ki ni ko je ki ami kan sokale fun un lati odo Oluwa re?” Nitori naa, so pe: “Ti Allahu ni ikoko. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً مِنْ بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُمْ إِذَا لَهُمْ مَكْرٌ فِي آيَاتِنَا ۚ قُلِ اللَّهُ أَسْرَعُ مَكْرًا ۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكْتُبُونَ مَا تَمْكُرُونَ
Nigba ti A ba fun awon eniyan ni idera kan towo leyin ti inira ti fowo ba won, nigba naa ni won maa dete si awon ayah Wa. So pe: “Allahu yara julo nibi ete. Dajudaju awon Ojise Wa n se akosile ohun ti e n da lete.”

Choose other languages: