Quran Apps in many lanuages:

Surah Ta-Ha Ayahs #84 Translated in Yoruba

يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ قَدْ أَنْجَيْنَاكُمْ مِنْ عَدُوِّكُمْ وَوَاعَدْنَاكُمْ جَانِبَ الطُّورِ الْأَيْمَنَ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكُمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ
Eyin omo ’Isro’il, dajudaju A ti gba yin la lowo ota yin. A si ba yin se adehun egbe otun apata. A si so ohun mimu monu ati ohun jije salwa kale fun yin
كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَلَا تَطْغَوْا فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبِي ۖ وَمَنْ يَحْلِلْ عَلَيْهِ غَضَبِي فَقَدْ هَوَىٰ
E je ninu awon nnkan daadaa ti A pa lese fun yin. E ma si koja enu ala ninu re nitori ki ibinu Mi ma baa ko le yin lori. Enikeni ti ibinu Mi ba si ko le lori, dajudaju o ti jabo (sinu iparun)
وَإِنِّي لَغَفَّارٌ لِمَنْ تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا ثُمَّ اهْتَدَىٰ
Dajudaju Emi ni Alaforijin fun enikeni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, leyin naa ti o tun tele imona
وَمَا أَعْجَلَكَ عَنْ قَوْمِكَ يَا مُوسَىٰ
Ki ni o mu o kanju ya awon eniyan re sile, Musa
قَالَ هُمْ أُولَاءِ عَلَىٰ أَثَرِي وَعَجِلْتُ إِلَيْكَ رَبِّ لِتَرْضَىٰ
O so pe: “Awon niwonyi ti won n to oripa mi bo (leyin mi). Emi si kanju wa sodo Re nitori ki O le yonu si mi ni, Oluwa mi.”

Choose other languages: