Quran Apps in many lanuages:

Surah Ta-Ha Ayahs #75 Translated in Yoruba

قَالَ آمَنْتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ ۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُمْ مِنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ فِي جُذُوعِ النَّخْلِ وَلَتَعْلَمُنَّ أَيُّنَا أَشَدُّ عَذَابًا وَأَبْقَىٰ
(Fir‘aon) wi pe: "Se e ti gba a gbo siwaju ki ng to yonda fun yin? Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Nitori naa, dajudaju mo maa ge awon owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Dajudaju mo tun maa kan yin mo awon igi dabinu. Dajudaju eyin yoo mo ewo ninu wa ni iya (re) yoo le julo, ti o si maa pe julo
قَالُوا لَنْ نُؤْثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَاءَنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالَّذِي فَطَرَنَا ۖ فَاقْضِ مَا أَنْتَ قَاضٍ ۖ إِنَّمَا تَقْضِي هَٰذِهِ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا
(Awon opidan) so pe: "Awa ko nii gbola fun o lori ohun ti o de ba wa ninu awon eri t’o daju, (a o si nii gbola fun o lori) Eni ti O seda wa. Nitori naa, da ohun ti o ba fe da lejo. Ile aye yii nikan ni o ti le dajo
إِنَّا آمَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغْفِرَ لَنَا خَطَايَانَا وَمَا أَكْرَهْتَنَا عَلَيْهِ مِنَ السِّحْرِ ۗ وَاللَّهُ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ
Dajudaju awa gba Oluwa wa gbo nitori ki O le se aforijin awon ese wa fun wa ati ohun ti o je wa nipa se ninu idan pipa. Allahu loore julo, O si maa wa titi laelae
إِنَّهُ مَنْ يَأْتِ رَبَّهُ مُجْرِمًا فَإِنَّ لَهُ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ
Dajudaju enikeni ti o ba wa ba Oluwa re ni (ipo) elese, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un. Ko nii ku sinu re, ko si nii wa laaye
وَمَنْ يَأْتِهِ مُؤْمِنًا قَدْ عَمِلَ الصَّالِحَاتِ فَأُولَٰئِكَ لَهُمُ الدَّرَجَاتُ الْعُلَىٰ
Enikeni ti o ba si wa ba A (gege bi) onigbagbo ododo, ti o si ti se ise rere, awon wonyen ni awon ipo giga n be fun

Choose other languages: