Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #50 Translated in Yoruba

قُلْ إِنَّمَا أَعِظُكُمْ بِوَاحِدَةٍ ۖ أَنْ تَقُومُوا لِلَّهِ مَثْنَىٰ وَفُرَادَىٰ ثُمَّ تَتَفَكَّرُوا ۚ مَا بِصَاحِبِكُمْ مِنْ جِنَّةٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا نَذِيرٌ لَكُمْ بَيْنَ يَدَيْ عَذَابٍ شَدِيدٍ
So pe: “Ohun kan soso ni mo n se waasi re fun yin pe, e duro nitori ti Allahu ni meji ati ni eyo kookan. Leyin naa, ki e ronu jinle. Ko si alujannu kan lara eni yin. Ko si je kini kan bi ko se olukilo fun yin siwaju iya lile kan.”
قُلْ مَا سَأَلْتُكُمْ مِنْ أَجْرٍ فَهُوَ لَكُمْ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللَّهِ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
So pe: “Emi ko bi yin leere owo-oya kan, eyin le kuku lowo yin. Ko si owo oya mi (lodo eni kan) afi lodo Allahu. Oun si ni Arinu-rode gbogbo nnkan.”
قُلْ إِنَّ رَبِّي يَقْذِفُ بِالْحَقِّ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
So pe: “Dajudaju Oluwa mi, Onimo-ikoko l’O n mu ododo wa.”
قُلْ جَاءَ الْحَقُّ وَمَا يُبْدِئُ الْبَاطِلُ وَمَا يُعِيدُ
So pe: “Ododo ti de. Iro (esu) ko le mu nnkan be, ko si le da nnkan pada (leyin to ti ku).”
قُلْ إِنْ ضَلَلْتُ فَإِنَّمَا أَضِلُّ عَلَىٰ نَفْسِي ۖ وَإِنِ اهْتَدَيْتُ فَبِمَا يُوحِي إِلَيَّ رَبِّي ۚ إِنَّهُ سَمِيعٌ قَرِيبٌ
So pe: “Ti mo ba sina, mo sina fun emi ara mi ni. Ti mo ba si mona, nipa ohun ti Oluwa mi fi ranse si mi ni imisi ni. Dajudaju Oun ni Olugbo, Alasun-unmo eda.”

Choose other languages: