Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #47 Translated in Yoruba

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا رَجُلٌ يُرِيدُ أَنْ يَصُدَّكُمْ عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُكُمْ وَقَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا إِفْكٌ مُفْتَرًى ۚ وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, won a wi pe: “Ki ni eyi bi ko se okunrin kan ti o fe se yin lori kuro nibi nnkan ti awon baba yin n josin fun.” Won tun wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro.” Ati pe awon t’o sai gbagbo wi nipa ododo nigba ti o de ba won pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”
وَمَا آتَيْنَاهُمْ مِنْ كُتُبٍ يَدْرُسُونَهَا ۖ وَمَا أَرْسَلْنَا إِلَيْهِمْ قَبْلَكَ مِنْ نَذِيرٍ
A o fun won ni awon tira kan kan ti won n ko eko ninu re, A o si ran olukilo kan kan si won siwaju re
وَكَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ وَمَا بَلَغُوا مِعْشَارَ مَا آتَيْنَاهُمْ فَكَذَّبُوا رُسُلِي ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Awon t’o siwaju won naa pe ododo niro. (Owo awon wonyi) ko si ti i te ida kan ida mewaa ninu ohun ti A fun (awon t’o siwaju). Sibesibe won pe awon Ojise Mi ni opuro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
قُلْ إِنَّمَا أَعِظُكُمْ بِوَاحِدَةٍ ۖ أَنْ تَقُومُوا لِلَّهِ مَثْنَىٰ وَفُرَادَىٰ ثُمَّ تَتَفَكَّرُوا ۚ مَا بِصَاحِبِكُمْ مِنْ جِنَّةٍ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا نَذِيرٌ لَكُمْ بَيْنَ يَدَيْ عَذَابٍ شَدِيدٍ
So pe: “Ohun kan soso ni mo n se waasi re fun yin pe, e duro nitori ti Allahu ni meji ati ni eyo kookan. Leyin naa, ki e ronu jinle. Ko si alujannu kan lara eni yin. Ko si je kini kan bi ko se olukilo fun yin siwaju iya lile kan.”
قُلْ مَا سَأَلْتُكُمْ مِنْ أَجْرٍ فَهُوَ لَكُمْ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللَّهِ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
So pe: “Emi ko bi yin leere owo-oya kan, eyin le kuku lowo yin. Ko si owo oya mi (lodo eni kan) afi lodo Allahu. Oun si ni Arinu-rode gbogbo nnkan.”

Choose other languages: