Quran Apps in many lanuages:

Surah Luqman Ayahs #32 Translated in Yoruba

مَا خَلْقُكُمْ وَلَا بَعْثُكُمْ إِلَّا كَنَفْسٍ وَاحِدَةٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Iseda yin ati ajinde yin ko tayo bi (iseda ati ajinde) emi eyo kan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ كُلٌّ يَجْرِي إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى وَأَنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O n ti oru bo inu osan, O n ti osan bo inu oru, O si ro oorun ati osupa? Ikookan won si n rin titi di gbedeke akoko kan. Ati pe (se o o ri i pe) dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ الْبَاطِلُ وَأَنَّ اللَّهَ هُوَ الْعَلِيُّ الْكَبِيرُ
Iyen nitori pe, dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, O ga, O tobi
أَلَمْ تَرَ أَنَّ الْفُلْكَ تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِنِعْمَتِ اللَّهِ لِيُرِيَكُمْ مِنْ آيَاتِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
Se o o ri i pe dajudaju oko oju-omi n rin ni oju omi pelu idera Re, (sebi) nitori ki (Allahu) le fi han yin ninu awon ami Re ni? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe
وَإِذَا غَشِيَهُمْ مَوْجٌ كَالظُّلَلِ دَعَوُا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ فَلَمَّا نَجَّاهُمْ إِلَى الْبَرِّ فَمِنْهُمْ مُقْتَصِدٌ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا كُلُّ خَتَّارٍ كَفُورٍ
Nigba ti igbi omi ba bo won mole daru bi awon apata ati esujo, won a pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Nigba ti O ba si gba won la sori ile, onideede si maa wa ninu won. Ko si si eni t’o maa tako awon ayah Wa afi gbogbo odale, alaimoore

Choose other languages: