Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #5 Translated in Yoruba

الر ۚ كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ إِلَيْكَ لِتُخْرِجَ النَّاسَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ بِإِذْنِ رَبِّهِمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ
’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira kan ti A sokale fun o nitori ki o le mu awon eniyan kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Oluwa won. (Won yo si bo) si ona Alagbara, Olope (ti ope to si)
اللَّهِ الَّذِي لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَوَيْلٌ لِلْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ شَدِيدٍ
Allahu, Eni ti O ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Egbe ni fun awon alaigbagbo nibi iya lile
الَّذِينَ يَسْتَحِبُّونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا عَلَى الْآخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ
Awon t’o n feran isemi aye ju torun, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo; awon wonyen wa ninu isina t’o jinna
وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ رَسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوْمِهِ لِيُبَيِّنَ لَهُمْ ۖ فَيُضِلُّ اللَّهُ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
A o ran Ojise kan nise afi pelu ede ijo re1 nitori ki o le salaye (esin) fun won. Nigba naa, Allahu yoo si enikeni ti O ba fe lona. O si maa to enikeni ti O ba fe sona; Oun ni Alagbara, Ologbon
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا أَنْ أَخْرِجْ قَوْمَكَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ وَذَكِّرْهُمْ بِأَيَّامِ اللَّهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
A kuku fi awon ayah Wa ran (Anabi) Musa nise pe: “Mu ijo re kuro lati inu awon okunkun bo sinu imole. Ki o si ran won leti awon idera Allahu (lori won).” Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

Choose other languages: