Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #6 Translated in Yoruba

اللَّهِ الَّذِي لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَوَيْلٌ لِلْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ شَدِيدٍ
Allahu, Eni ti O ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Egbe ni fun awon alaigbagbo nibi iya lile
الَّذِينَ يَسْتَحِبُّونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا عَلَى الْآخِرَةِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَيَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ بَعِيدٍ
Awon t’o n feran isemi aye ju torun, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo; awon wonyen wa ninu isina t’o jinna
وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ رَسُولٍ إِلَّا بِلِسَانِ قَوْمِهِ لِيُبَيِّنَ لَهُمْ ۖ فَيُضِلُّ اللَّهُ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
A o ran Ojise kan nise afi pelu ede ijo re1 nitori ki o le salaye (esin) fun won. Nigba naa, Allahu yoo si enikeni ti O ba fe lona. O si maa to enikeni ti O ba fe sona; Oun ni Alagbara, Ologbon
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا أَنْ أَخْرِجْ قَوْمَكَ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ وَذَكِّرْهُمْ بِأَيَّامِ اللَّهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
A kuku fi awon ayah Wa ran (Anabi) Musa nise pe: “Mu ijo re kuro lati inu awon okunkun bo sinu imole. Ki o si ran won leti awon idera Allahu (lori won).” Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ أَنْجَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe e ranti ike Allahu lori yin nigba ti O gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin; won n dunnbu awon omokunrin yin, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin

Choose other languages: