Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #96 Translated in Yoruba

قَالَ يَا قَوْمِ أَرَهْطِي أَعَزُّ عَلَيْكُمْ مِنَ اللَّهِ وَاتَّخَذْتُمُوهُ وَرَاءَكُمْ ظِهْرِيًّا ۖ إِنَّ رَبِّي بِمَا تَعْمَلُونَ مُحِيطٌ
O so pe: “Eyin ijo mi, se ebi mi lo lagbara loju yin ju Allahu? E si so Allahu di Eni ti e koyin kopako si! Dajudaju Oluwa mi ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
وَيَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ سَوْفَ تَعْلَمُونَ مَنْ يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَمَنْ هُوَ كَاذِبٌ ۖ وَارْتَقِبُوا إِنِّي مَعَكُمْ رَقِيبٌ
Eyin ijo mi, e maa se bi e ti fe ninu esin yin, dajudaju emi yoo maa ba esin mi lo. Laipe eyin yoo mo eni ti iya maa de ba, ti o maa yepere re, (eyin yo si mo) ta ni opuro. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ti mo n reti (ikangun oro yin).”
وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا شُعَيْبًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَأَخَذَتِ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Su‘aeb ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. Ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
كَأَنْ لَمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا بُعْدًا لِمَدْيَنَ كَمَا بَعِدَتْ ثَمُودُ
Afi bi eni pe won ko gbe inu ilu naa ri. Gbo, ijinna si ike n be fun iran Modyan gege bi iran Thamud se jinna si ike
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا وَسُلْطَانٍ مُبِينٍ
Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri ponnbele ran (Anabi) Musa

Choose other languages: