Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #91 Translated in Yoruba

قَالُوا يَا شُعَيْبُ أَصَلَاتُكَ تَأْمُرُكَ أَنْ نَتْرُكَ مَا يَعْبُدُ آبَاؤُنَا أَوْ أَنْ نَفْعَلَ فِي أَمْوَالِنَا مَا نَشَاءُ ۖ إِنَّكَ لَأَنْتَ الْحَلِيمُ الرَّشِيدُ
Won wi pe: "Su‘aeb, se irun re l’o n pa o lase pe ki a gbe ohun ti awon baba wa n josin fun ju sile, tabi (irun re lo n ko fun wa) lati se ohun ti a ba fe ninu dukia wa? Dajudaju iwo ma ni alafarada, olumona (loju ara re niyen)
قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كُنْتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَرَزَقَنِي مِنْهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أُخَالِفَكُمْ إِلَىٰ مَا أَنْهَاكُمْ عَنْهُ ۚ إِنْ أُرِيدُ إِلَّا الْإِصْلَاحَ مَا اسْتَطَعْتُ ۚ وَمَا تَوْفِيقِي إِلَّا بِاللَّهِ ۚ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ أُنِيبُ
O so pe: “Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti (Oluwa mi) si fun mi ni arisiki lati odo Re ni arisiki t’o dara (se ki ng maa je haramu pelu re ni?). Emi ko si fe yapa yin nipa nnkan ti mo n ko fun yin (iyen ni pe, emi naa n lo ohun ti mo n so fun yin). Ko si ohun ti mo fe bi ko se atunse pelu bi mo se lagbara mo. Ko si konge imona kan fun mi bi ko se pelu (iyonda) Allahu. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri si (fun ironupiwada)
وَيَا قَوْمِ لَا يَجْرِمَنَّكُمْ شِقَاقِي أَنْ يُصِيبَكُمْ مِثْلُ مَا أَصَابَ قَوْمَ نُوحٍ أَوْ قَوْمَ هُودٍ أَوْ قَوْمَ صَالِحٍ ۚ وَمَا قَوْمُ لُوطٍ مِنْكُمْ بِبَعِيدٍ
Eyin ijo mi, e ma se je ki (bi) e se n yapa mi mu yin lugbadi iru ohun ti o sele si ijo (Anabi) Nuh tabi ijo (Anabi) Hud tabi ijo (Anabi) Solih. Ijo (Anabi) Lut ko si jinna si yin
وَاسْتَغْفِرُوا رَبَّكُمْ ثُمَّ تُوبُوا إِلَيْهِ ۚ إِنَّ رَبِّي رَحِيمٌ وَدُودٌ
Ki e si toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu, Ololufe (eda).”
قَالُوا يَا شُعَيْبُ مَا نَفْقَهُ كَثِيرًا مِمَّا تَقُولُ وَإِنَّا لَنَرَاكَ فِينَا ضَعِيفًا ۖ وَلَوْلَا رَهْطُكَ لَرَجَمْنَاكَ ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْنَا بِعَزِيزٍ
Won wi pe: "Su‘aeb, a o gbo agboye opolopo ninu ohun ti o n so. Dajudaju awa si n ri o ni ole laaarin wa. Ti ko ba je pe nitori ti ebi re ni, a iba ti ku o loko pa; iwo ko si nii lagbara kan lori wa

Choose other languages: