Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #44 Translated in Yoruba

حَتَّىٰ إِذَا جَاءَ أَمْرُنَا وَفَارَ التَّنُّورُ قُلْنَا احْمِلْ فِيهَا مِنْ كُلٍّ زَوْجَيْنِ اثْنَيْنِ وَأَهْلَكَ إِلَّا مَنْ سَبَقَ عَلَيْهِ الْقَوْلُ وَمَنْ آمَنَ ۚ وَمَا آمَنَ مَعَهُ إِلَّا قَلِيلٌ
(Bayii ni oro wa) titi di igba ti ase Wa de, omi si seyo gbuu lati oju-aro (ti won ti n se buredi). A so pe: "Ko gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re sinu oko oju-omi - ayafi eni ti oro naa ti ko le lori (fun iparun) - ati enikeni t’o gbagbo ni ododo. Ko si si eni t’o ni igbagbo ododo pelu re afi awon die
وَقَالَ ارْكَبُوا فِيهَا بِسْمِ اللَّهِ مَجْرَاهَا وَمُرْسَاهَا ۚ إِنَّ رَبِّي لَغَفُورٌ رَحِيمٌ
(Anabi Nuh) so pe: "E wo inu oko oju-omi naa. O maa rin, o si maa gunle ni oruko Allahu. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun
وَهِيَ تَجْرِي بِهِمْ فِي مَوْجٍ كَالْجِبَالِ وَنَادَىٰ نُوحٌ ابْنَهُ وَكَانَ فِي مَعْزِلٍ يَا بُنَيَّ ارْكَبْ مَعَنَا وَلَا تَكُنْ مَعَ الْكَافِرِينَ
O si n gbe won lo ninu igbi omi t’o da bi apata. (Anabi Nuh) si ke si omokunrin re, ti o ti yara re soto: "Omokunrin mi, gun oko oju-omi pelu wa. Ma si se wa pelu awon alaigbagbo
قَالَ سَآوِي إِلَىٰ جَبَلٍ يَعْصِمُنِي مِنَ الْمَاءِ ۚ قَالَ لَا عَاصِمَ الْيَوْمَ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ إِلَّا مَنْ رَحِمَ ۚ وَحَالَ بَيْنَهُمَا الْمَوْجُ فَكَانَ مِنَ الْمُغْرَقِينَ
O wi pe: “Emi yoo fori pamo sibi apata kan ti o maa la mi nibi omi.” (Anabi Nuh) so pe: "Ko si alaabo kan ni oni nibi ase Allahu afi eni ti Allahu ba saanu." Igbi omi si la awon mejeeji laaarin. O si di ara awon oluteri sinu omi
وَقِيلَ يَا أَرْضُ ابْلَعِي مَاءَكِ وَيَا سَمَاءُ أَقْلِعِي وَغِيضَ الْمَاءُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ وَاسْتَوَتْ عَلَى الْجُودِيِّ ۖ وَقِيلَ بُعْدًا لِلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
A so pe: "Ile, fa omi re mu. Sanmo, dawo (ojo) duro." Won si din omi ku. Oro iparun won si wa si imuse. (Oko oju-omi) si gunle sori apata Judi. A si so pe: “Ijinna rere si ike Allahu ni ti ijo alabosi.”

Choose other languages: