Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #18 Translated in Yoruba

فَإِلَّمْ يَسْتَجِيبُوا لَكُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا أُنْزِلَ بِعِلْمِ اللَّهِ وَأَنْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ مُسْلِمُونَ
Nigba naa ti won ko ba da yin lohun, ki e mo pe dajudaju won so (al-Ƙur’an) kale pelu imo Allahu. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, se eyin yoo di musulumi
مَنْ كَانَ يُرِيدُ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيْهِمْ أَعْمَالَهُمْ فِيهَا وَهُمْ فِيهَا لَا يُبْخَسُونَ
Enikeni ti o ba n fe isemi aye ati oso re, A oo san won ni esan ise won nile aye. A o si nii din kini kan ku fun won nile aye
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَيْسَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ إِلَّا النَّارُ ۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُوا فِيهَا وَبَاطِلٌ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon wonyen ni awon ti ko nii si kini kan fun mo ni Ojo Ikeyin afi Ina. Nnkan ti won gbele aye si maa baje. Ofo si ni ohun ti won n se nise
أَفَمَنْ كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّهِ وَيَتْلُوهُ شَاهِدٌ مِنْهُ وَمِنْ قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ أُولَٰئِكَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۚ وَمَنْ يَكْفُرْ بِهِ مِنَ الْأَحْزَابِ فَالنَّارُ مَوْعِدُهُ ۚ فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِنْهُ ۚ إِنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
Nje eni t’o n be lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re (iyen, Anabi s.a.w.), ti olujerii kan (iyen, molaika Jibril) si n ke al-Ƙur’an (fun un) lati odo Allahu, ti tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won), (nje Anabi yii jo olusina bi?) Awon (musulumi) wonyi ni won si gba a gbo ni ododo. Enikeni t’o ba sai gba a gbo ninu awon ijo (nasara, yehudi ati osebo), nigba naa Ina ni adehun re. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa al-Ƙur’an. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re, sugbon opolopo eniyan ni ko gbagbo
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا ۚ أُولَٰئِكَ يُعْرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمْ وَيَقُولُ الْأَشْهَادُ هَٰؤُلَاءِ الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ أَلَا لَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الظَّالِمِينَ
Ati pe ta ni o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu? Awon wonyen ni won yoo ko wa siwaju Oluwa won. Awon elerii (iyen, awon molaika) yo si maa so pe: "Awon wonyi ni awon t’o paro mo Oluwa won." Gbo, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alabosi

Choose other languages: