Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #83 Translated in Yoruba

اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَنْعَامَ لِتَرْكَبُوا مِنْهَا وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ
Allahu ni Eni ti O da awon eran-osin fun yin nitori ki e le maa gun ninu won. E o si maa je ninu won
وَلَكُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَلِتَبْلُغُوا عَلَيْهَا حَاجَةً فِي صُدُورِكُمْ وَعَلَيْهَا وَعَلَى الْفُلْكِ تُحْمَلُونَ
Awon anfaani (miiran) wa fun yin lara eran-osin. Ati nitori ki e le de ona jijin t’o wa lokan yin lori (gigun) won (kiri). E o si maa fi awon (eran-osin) ati oko oju-omi gbe awon eru
وَيُرِيكُمْ آيَاتِهِ فَأَيَّ آيَاتِ اللَّهِ تُنْكِرُونَ
(Allahu) n fi awon ami Re han yin. Nitori naa, ewo ninu awon ami Allahu l’e maa tako
أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَكْثَرَ مِنْهُمْ وَأَشَدَّ قُوَّةً وَآثَارًا فِي الْأَرْضِ فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won po (ni onka) ju won lo. Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe ohun ti won n se nise ko ro won loro (nibi iya)
فَلَمَّا جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَرِحُوا بِمَا عِنْدَهُمْ مِنَ الْعِلْمِ وَحَاقَ بِهِمْ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ
Nigba ti awon Ojise mu awon eri t’o yanju wa ba won, won yo ayoporo nitori ohun t’o wa lodo won ninu imo (aye). Ohun ti won si n fi se yeye si diya t’o yi won po

Choose other languages: