Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #61 Translated in Yoruba

لَخَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ أَكْبَرُ مِنْ خَلْقِ النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Dajudaju iseda awon sanmo ati ile tobi ju iseda awon eniyan; sugbon opolopo awon eniyan ni ko mo
وَمَا يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَلَا الْمُسِيءُ ۚ قَلِيلًا مَا تَتَذَكَّرُونَ
Afoju ati oluriran ko dogba. Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ati onise-aburu (ko dogba). Die l’e n lo ninu iranti
إِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ لَا رَيْبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يُؤْمِنُونَ
Dajudaju Akoko naa n bo, ko si si iyemeji ninu re. Sugbon opolopo awon eniyan ni ko gbagbo
وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ
Oluwa yin so pe: "E pe Mi, ki Ng jepe yin. Dajudaju awon t’o n segberaga nipa jijosin fun Mi, won yoo wo inu ina Jahanamo ni eni yepere
اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ
Allahu ni Eni ti O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O si se) osan (nitori ki e le fi) riran. Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Un)

Choose other languages: