Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #37 Translated in Yoruba

يَوْمَ تُوَلُّونَ مُدْبِرِينَ مَا لَكُمْ مِنَ اللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۗ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ
Ojo ti e maa peyinda lati sa lo; ko si nii si alaabo kan fun yin lodo Allahu. Ati pe eni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un
وَلَقَدْ جَاءَكُمْ يُوسُفُ مِنْ قَبْلُ بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا زِلْتُمْ فِي شَكٍّ مِمَّا جَاءَكُمْ بِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا هَلَكَ قُلْتُمْ لَنْ يَبْعَثَ اللَّهُ مِنْ بَعْدِهِ رَسُولًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَنْ هُوَ مُسْرِفٌ مُرْتَابٌ
Ati pe dajudaju (Anabi) Yusuf ti to yin wa siwaju pelu awon alaye oro t’o yanju, sugbon eyin ko ye wa ninu iyemeji nipa ohun ti o mu wa ba yin titi di igba ti o fi ku, ti e fi wi pe: "Allahu ko nii gbe Ojise kan dide mo leyin re." Bayen ni Allahu se n so eni ti o je alaseju, oniyemeji nu
الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ بِغَيْرِ سُلْطَانٍ أَتَاهُمْ ۖ كَبُرَ مَقْتًا عِنْدَ اللَّهِ وَعِنْدَ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلْبِ مُتَكَبِّرٍ جَبَّارٍ
Awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laisi eri kan ti o de ba won. Ese nla si ni ni odo Allahu ati ni odo awon t’o gbagbo ni ododo. Bayen ni Allahu se n fi edidi bo gbogbo okan onigbeeraga, ajeninipa.”
وَقَالَ فِرْعَوْنُ يَا هَامَانُ ابْنِ لِي صَرْحًا لَعَلِّي أَبْلُغُ الْأَسْبَابَ
Fir‘aon wi pe: "Hamon, mo ile giga fiofio kan fun mi nitori ki emi le de awon oju ona naa
أَسْبَابَ السَّمَاوَاتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُ كَاذِبًا ۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرْعَوْنَ سُوءُ عَمَلِهِ وَصُدَّ عَنِ السَّبِيلِ ۚ وَمَا كَيْدُ فِرْعَوْنَ إِلَّا فِي تَبَابٍ
Awon oju ona (inu) sanmo ni, nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa nitori pe dajudaju emi n ro o si opuro." Bayen ni won se ise aburu (owo) Fir‘aon ni oso fun un. Won si seri re kuro loju ona (esin Allahu). Ete Fir‘aon ko si wa ninu kini kan bi ko se ninu ofo

Choose other languages: