Quran Apps in many lanuages:

Surah Fussilat Ayahs #23 Translated in Yoruba

وَيَوْمَ يُحْشَرُ أَعْدَاءُ اللَّهِ إِلَى النَّارِ فَهُمْ يُوزَعُونَ
Ni ojo ti won maa ko awon ota Allahu jo sibi Ina, won yo si ko awon eni akoko won papo mo awon eni ikeyin won
حَتَّىٰ إِذَا مَا جَاءُوهَا شَهِدَ عَلَيْهِمْ سَمْعُهُمْ وَأَبْصَارُهُمْ وَجُلُودُهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
titi di igba ti won ba de ibe tan, igboro won, iriran won ati awo ara won yo si maa jerii le won lori nipa ohun ti won n se nise
وَقَالُوا لِجُلُودِهِمْ لِمَ شَهِدْتُمْ عَلَيْنَا ۖ قَالُوا أَنْطَقَنَا اللَّهُ الَّذِي أَنْطَقَ كُلَّ شَيْءٍ وَهُوَ خَلَقَكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Won yoo wi fun awo ara won pe: "Nitori ki ni e se jerii le wa lori na?" Won yoo so pe: "Allahu, Eni ti O fun gbogbo nnkan ni oro so, Oun l’O fun wa ni oro so. Oun si l’O seda yin nigba akoko. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
وَمَا كُنْتُمْ تَسْتَتِرُونَ أَنْ يَشْهَدَ عَلَيْكُمْ سَمْعُكُمْ وَلَا أَبْصَارُكُمْ وَلَا جُلُودُكُمْ وَلَٰكِنْ ظَنَنْتُمْ أَنَّ اللَّهَ لَا يَعْلَمُ كَثِيرًا مِمَّا تَعْمَلُونَ
Eyin ko le para yin mo (kuro nibi ese, nitori) ki igboro yin, iriran yin ati awo ara yin ma fi le jerii le yin lori. Sugbon e lero pe dajudaju Allahu ko mo opolopo ninu ohun ti e n se nise
وَذَٰلِكُمْ ظَنُّكُمُ الَّذِي ظَنَنْتُمْ بِرَبِّكُمْ أَرْدَاكُمْ فَأَصْبَحْتُمْ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Iyen, ero yin ti e lero si Oluwa yin lo ko iparun ba yin. E si di eni ofo

Choose other languages: