Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #38 Translated in Yoruba

وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَذْهَبَ عَنَّا الْحَزَنَ ۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٌ شَكُورٌ
Won yoo so pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu ibanuje kuro fun wa. Dajudaju Oluwa wa ni Alaforijin, Olope
الَّذِي أَحَلَّنَا دَارَ الْمُقَامَةِ مِنْ فَضْلِهِ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٌ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٌ
Eni ti O so wa kale sinu ibugbe gbere ninu oore ajulo Re. Wahala kan ko nii kan wa ninu re. Ikaaare kan ko si nii ba wa ninu re
وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقْضَىٰ عَلَيْهِمْ فَيَمُوتُوا وَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ مِنْ عَذَابِهَا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي كُلَّ كَفُورٍ
Ati pe awon t’o sai gbagbo, ina Jahnamo n be fun won. A o nii pa won (sinu re), ambosibosi pe won yoo ku. A o si nii gbe iya re fuye fun won. Bayen ni A se n san gbogbo awon alaigbagbo ni esan
وَهُمْ يَصْطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَا أَخْرِجْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ ۚ أَوَلَمْ نُعَمِّرْكُمْ مَا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَنْ تَذَكَّرَ وَجَاءَكُمُ النَّذِيرُ ۖ فَذُوقُوا فَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ نَصِيرٍ
Won yoo maa logun iranlowo ninu re pe: “Oluwa wa, mu wa jade nitori ki a le lo se ise rere, yato si eyi ti a maa n se.” Se A o fun yin ni emi gigun lo to fun eni ti o ba fe lo isiti lati ri i lo ninu asiko naa ni? Olukilo si wa ba yin. Nitori naa, e to iya wo. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi
إِنَّ اللَّهَ عَالِمُ غَيْبِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko awon sanmo ati ile. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

Choose other languages: