Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zamar Ayahs #42 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ مَنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۚ قُلْ أَفَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ إِنْ أَرَادَنِيَ اللَّهُ بِضُرٍّ هَلْ هُنَّ كَاشِفَاتُ ضُرِّهِ أَوْ أَرَادَنِي بِرَحْمَةٍ هَلْ هُنَّ مُمْسِكَاتُ رَحْمَتِهِ ۚ قُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ ۖ عَلَيْهِ يَتَوَكَّلُ الْمُتَوَكِّلُونَ
Dajudaju ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." So pe: "E so fun mi nipa awon nnkan ti e n pe leyin Allahu, ti Allahu ba gbero inira kan ro mi, nje won le mu inira Re kuro fun mi? Tabi ti O ba gbero ike kan si mi, nje won le da ike Re duro bi?" So pe: "Allahu to fun mi. Oun si ni awon olugbarale n gbarale
قُلْ يَا قَوْمِ اعْمَلُوا عَلَىٰ مَكَانَتِكُمْ إِنِّي عَامِلٌ ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
So pe: "Eyin eniyan mi, e se tiyin ni aye yin. Emi naa n se temi. Nitori naa, laipe e maa mo
مَنْ يَأْتِيهِ عَذَابٌ يُخْزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيْهِ عَذَابٌ مُقِيمٌ
eni ti iya ti o maa yepere re maa de ba, ti iya gbere si maa ko le lori
إِنَّا أَنْزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ لِلنَّاسِ بِالْحَقِّ ۖ فَمَنِ اهْتَدَىٰ فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَا أَنْتَ عَلَيْهِمْ بِوَكِيلٍ
Dajudaju Awa so Tira kale fun o pelu ododo (ki o le fi se iranti) fun awon eniyan. Nitori naa, eni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Eni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Iwo si ko ni oluso lori won
اللَّهُ يَتَوَفَّى الْأَنْفُسَ حِينَ مَوْتِهَا وَالَّتِي لَمْ تَمُتْ فِي مَنَامِهَا ۖ فَيُمْسِكُ الَّتِي قَضَىٰ عَلَيْهَا الْمَوْتَ وَيُرْسِلُ الْأُخْرَىٰ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Allahu l’O n gba awon emi ni akoko iku won ati (awon emi) ti ko ku soju oorun won. O n mu (awon emi) ti O ti pebubu iku le lori mole. O si n fi awon yooku sile titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

Choose other languages: