Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #82 Translated in Yoruba

أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُمْ وَأَنَّ اللَّهَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ
Se won ko mo pe Allahu mo asiri won ati oro ateso won, ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon ikoko
الَّذِينَ يَلْمِزُونَ الْمُطَّوِّعِينَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ فِي الصَّدَقَاتِ وَالَّذِينَ لَا يَجِدُونَ إِلَّا جُهْدَهُمْ فَيَسْخَرُونَ مِنْهُمْ ۙ سَخِرَ اللَّهُ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Awon t’o n bu awon olutore-aanu ninu awon onigbagbo ododo lori ore tita ati awon ti ko ri nnkan kan tayo iwon agbara won, won si n fi won se yeye, Allahu fi awon naa se yeye. Iya eleta-elero si wa fun won
اسْتَغْفِرْ لَهُمْ أَوْ لَا تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ إِنْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ سَبْعِينَ مَرَّةً فَلَنْ يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
Yala o toro aforijin fun won tabi o o toro aforijin fun won – koda ki o toro aforijin fun won nigba aadorin – Allahu ko nii forijin won. Iyen nitori pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje
فَرِحَ الْمُخَلَّفُونَ بِمَقْعَدِهِمْ خِلَافَ رَسُولِ اللَّهِ وَكَرِهُوا أَنْ يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَقَالُوا لَا تَنْفِرُوا فِي الْحَرِّ ۗ قُلْ نَارُ جَهَنَّمَ أَشَدُّ حَرًّا ۚ لَوْ كَانُوا يَفْقَهُونَ
Awon olusaseyin fun ogun esin dunnu si jijokoo sinu ile won leyin Ojise Allahu. Won si korira lati fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu. Won tun wi pe: “E ma lo jagun ninu ooru gbigbona.” So pe: “Ina Jahanamo le julo ni gbigbona, ti o ba je pe won gbo agboye oro.”
فَلْيَضْحَكُوا قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا كَثِيرًا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
Nitori naa, ki won rerin-in die, ki won si sunkun pupo; (o je) esan (fun) ohun ti won n se nise

Choose other languages: