Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #42 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَا لَكُمْ إِذَا قِيلَ لَكُمُ انْفِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ اثَّاقَلْتُمْ إِلَى الْأَرْضِ ۚ أَرَضِيتُمْ بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا مِنَ الْآخِرَةِ ۚ فَمَا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا فِي الْآخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki ni o mu yin ti o fi je pe nigba ti A ba so fun yin pe ki e jade (lati jagun) loju ona (esin) Allahu, (igba naa ni) e maa kandi mole! Se e yonu si isemi aye (yii) ju ti orun ni? Igbadun isemi aye (yii) ko si je kini kan ninu ti orun afi die
إِلَّا تَنْفِرُوا يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَيَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّوهُ شَيْئًا ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Afi ki e tu jade (sogun esin) ni Allahu ko fi nii je yin niya eleta-elero ati pe ni ko fi nii fi ijo to yato si yin paaro yin. E ko si le fi kini kan ko inira ba (Allahu). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
إِلَّا تَنْصُرُوهُ فَقَدْ نَصَرَهُ اللَّهُ إِذْ أَخْرَجَهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ثَانِيَ اثْنَيْنِ إِذْ هُمَا فِي الْغَارِ إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ اللَّهَ مَعَنَا ۖ فَأَنْزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَيْهِ وَأَيَّدَهُ بِجُنُودٍ لَمْ تَرَوْهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ الَّذِينَ كَفَرُوا السُّفْلَىٰ ۗ وَكَلِمَةُ اللَّهِ هِيَ الْعُلْيَا ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Afi ki e ran an lowo, Allahu kuku ti ran an lowo nigba ti awon t’o sai gbagbo le e jade (kuro ninu ilu). O si je okan ninu awon meji.1 Nigba ti awon mejeeji wa ninu ogbun, ti (Anabi) si n so fun olubarin re pe: "Ma se banuje, dajudaju Allahu wa pelu wa."2 Nigba naa, Allahu so ifayabale Re kale fun un. O fi awon omo ogun kan ti e o foju ri ran an lowo. O si mu oro awon t’o sai gbagbo wale. Oro Allahu, ohun l’o si leke. Allahu si ni Alagbara, Ologbon
انْفِرُوا خِفَافًا وَثِقَالًا وَجَاهِدُوا بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ
E tu jade (fun ogun esin) pelu okun ati iroju. Ki e si fi awon dukia yin ati emi yin jagun fun esin Allahu. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo
لَوْ كَانَ عَرَضًا قَرِيبًا وَسَفَرًا قَاصِدًا لَاتَّبَعُوكَ وَلَٰكِنْ بَعُدَتْ عَلَيْهِمُ الشُّقَّةُ ۚ وَسَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَوِ اسْتَطَعْنَا لَخَرَجْنَا مَعَكُمْ يُهْلِكُونَ أَنْفُسَهُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Ti o ba je pe nnkan igbadun (oro ogun) arowoto ati irin-ajo ti ko jinna (l’o pe won si ni), won iba tele o. Sugbon irin-ajo ogun Tabuk jinna loju won. Won yo si maa fi Allahu bura pe: “Ti o ba je pe a lagbara ni, awa iba jade (fun ogun esin) pelu yin.” – Won si n ko iparun ba emi ara won (nipa sise isobe-selu.) – Allahu si mo pe dajudaju opuro ni won

Choose other languages: