Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #44 Translated in Yoruba

إِلَّا تَنْصُرُوهُ فَقَدْ نَصَرَهُ اللَّهُ إِذْ أَخْرَجَهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ثَانِيَ اثْنَيْنِ إِذْ هُمَا فِي الْغَارِ إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ اللَّهَ مَعَنَا ۖ فَأَنْزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَيْهِ وَأَيَّدَهُ بِجُنُودٍ لَمْ تَرَوْهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ الَّذِينَ كَفَرُوا السُّفْلَىٰ ۗ وَكَلِمَةُ اللَّهِ هِيَ الْعُلْيَا ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Afi ki e ran an lowo, Allahu kuku ti ran an lowo nigba ti awon t’o sai gbagbo le e jade (kuro ninu ilu). O si je okan ninu awon meji.1 Nigba ti awon mejeeji wa ninu ogbun, ti (Anabi) si n so fun olubarin re pe: "Ma se banuje, dajudaju Allahu wa pelu wa."2 Nigba naa, Allahu so ifayabale Re kale fun un. O fi awon omo ogun kan ti e o foju ri ran an lowo. O si mu oro awon t’o sai gbagbo wale. Oro Allahu, ohun l’o si leke. Allahu si ni Alagbara, Ologbon
انْفِرُوا خِفَافًا وَثِقَالًا وَجَاهِدُوا بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ
E tu jade (fun ogun esin) pelu okun ati iroju. Ki e si fi awon dukia yin ati emi yin jagun fun esin Allahu. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo
لَوْ كَانَ عَرَضًا قَرِيبًا وَسَفَرًا قَاصِدًا لَاتَّبَعُوكَ وَلَٰكِنْ بَعُدَتْ عَلَيْهِمُ الشُّقَّةُ ۚ وَسَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَوِ اسْتَطَعْنَا لَخَرَجْنَا مَعَكُمْ يُهْلِكُونَ أَنْفُسَهُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Ti o ba je pe nnkan igbadun (oro ogun) arowoto ati irin-ajo ti ko jinna (l’o pe won si ni), won iba tele o. Sugbon irin-ajo ogun Tabuk jinna loju won. Won yo si maa fi Allahu bura pe: “Ti o ba je pe a lagbara ni, awa iba jade (fun ogun esin) pelu yin.” – Won si n ko iparun ba emi ara won (nipa sise isobe-selu.) – Allahu si mo pe dajudaju opuro ni won
عَفَا اللَّهُ عَنْكَ لِمَ أَذِنْتَ لَهُمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكَ الَّذِينَ صَدَقُوا وَتَعْلَمَ الْكَاذِبِينَ
Allahu ti samojukuro fun o. Ki lo mu o yonda fun won (pe ki won duro sile? Iwo iba ma se bee) titi oro awon t’o sododo yoo fi han si o kedere. Iwo yo si mo awon opuro
لَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ أَنْ يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin ko nii toro iyonda lodo re lati ma fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)

Choose other languages: