Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #110 Translated in Yoruba

وَآخَرُونَ مُرْجَوْنَ لِأَمْرِ اللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمْ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Won so oro awon yooku ro na fun ase Allahu; yala ki O je won niya tabi ki O gba ironupiwada won. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مَسْجِدًا ضِرَارًا وَكُفْرًا وَتَفْرِيقًا بَيْنَ الْمُؤْمِنِينَ وَإِرْصَادًا لِمَنْ حَارَبَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ مِنْ قَبْلُ ۚ وَلَيَحْلِفُنَّ إِنْ أَرَدْنَا إِلَّا الْحُسْنَىٰ ۖ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Awon t’o ko mosalasi lati fi da inira ati aigbagbo sile ati lati fi se opinya laaarin awon onigbagbo ododo ati lati fi se ibuba fun awon t’o gbogun ti Allahu ati Ojise Re ni isaaju – dajudaju won n bura pe “A o gbero kini kan bi ko se ohun rere.” – Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won
لَا تَقُمْ فِيهِ أَبَدًا ۚ لَمَسْجِدٌ أُسِّسَ عَلَى التَّقْوَىٰ مِنْ أَوَّلِ يَوْمٍ أَحَقُّ أَنْ تَقُومَ فِيهِ ۚ فِيهِ رِجَالٌ يُحِبُّونَ أَنْ يَتَطَهَّرُوا ۚ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُطَّهِّرِينَ
Ma se duro (kirun) ninu re laelae. Dajudaju mosalasi ti won ba fi ipile re lele lori iberu Allahu lati ojo akoko l’o letoo julo pe ki o duro (kirun) ninu re. Awon eniyan t’o nifee lati maa se imora wa ninu re. Allahu si feran awon olusemora
أَفَمَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ تَقْوَىٰ مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٍ خَيْرٌ أَمْ مَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٍ فَانْهَارَ بِهِ فِي نَارِ جَهَنَّمَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Nje eni ti o fi ipile ile mimo tire lele lori iberu Allahu ati iyonu (Re) l’o loore julo ni tabi eni ti o fi ipile ile mimo tire lele ni egbe kan leti ogbun t’o maa ye lule, ti o si maa ye e lese sinu ina Jahanamo? Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
لَا يَزَالُ بُنْيَانُهُمُ الَّذِي بَنَوْا رِيبَةً فِي قُلُوبِهِمْ إِلَّا أَنْ تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Ile won ti won mo kale ko nii ye ko iyemeji sinu okan won titi okan won yoo fi ja kelekele. Allahu si ni Onimo, Ologbon

Choose other languages: