Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #108 Translated in Yoruba

أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ هُوَ يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَأْخُذُ الصَّدَقَاتِ وَأَنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Se won ko mo pe dajudaju Allahu Oun l’O n gba ironupiwada lowo awon erusin Re, O si n gba awon ore, ati pe dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
وَقُلِ اعْمَلُوا فَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ وَالْمُؤْمِنُونَ ۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
So pe: "E sise. Allahu a ri ise yin, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo naa (maa ri i). Won si maa da yin pada sodo Onimo-ikoko-ati-gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
وَآخَرُونَ مُرْجَوْنَ لِأَمْرِ اللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمْ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Won so oro awon yooku ro na fun ase Allahu; yala ki O je won niya tabi ki O gba ironupiwada won. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مَسْجِدًا ضِرَارًا وَكُفْرًا وَتَفْرِيقًا بَيْنَ الْمُؤْمِنِينَ وَإِرْصَادًا لِمَنْ حَارَبَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ مِنْ قَبْلُ ۚ وَلَيَحْلِفُنَّ إِنْ أَرَدْنَا إِلَّا الْحُسْنَىٰ ۖ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Awon t’o ko mosalasi lati fi da inira ati aigbagbo sile ati lati fi se opinya laaarin awon onigbagbo ododo ati lati fi se ibuba fun awon t’o gbogun ti Allahu ati Ojise Re ni isaaju – dajudaju won n bura pe “A o gbero kini kan bi ko se ohun rere.” – Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won
لَا تَقُمْ فِيهِ أَبَدًا ۚ لَمَسْجِدٌ أُسِّسَ عَلَى التَّقْوَىٰ مِنْ أَوَّلِ يَوْمٍ أَحَقُّ أَنْ تَقُومَ فِيهِ ۚ فِيهِ رِجَالٌ يُحِبُّونَ أَنْ يَتَطَهَّرُوا ۚ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُطَّهِّرِينَ
Ma se duro (kirun) ninu re laelae. Dajudaju mosalasi ti won ba fi ipile re lele lori iberu Allahu lati ojo akoko l’o letoo julo pe ki o duro (kirun) ninu re. Awon eniyan t’o nifee lati maa se imora wa ninu re. Allahu si feran awon olusemora

Choose other languages: